Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa to wa nipinle Edo, ti fọwọ ofin mu awọn ọdaran mẹtẹẹta wọnyi, Ibrahim Sani, ẹni ọdun mẹtalelogun, Kabiru Ibrahim, ẹni ọdun mejilelaaadọta ati Abubakar Mohammed, ẹni ọdun mejilelọgbọn.
Ohun ti wọn tori ẹ ko sakolo ọlọpaa ni bi wọn ṣe fẹsun kan wọn pe wọn maa n ji awọn ọmọ keekeeke gbe. Wọn ni o ti pẹ diẹ tawọn ọdaran ti n ṣiṣẹ buruku yii lagbegbe wọn, ti wọn yoo si lọo ta awọn ọmọ ti wọn ba ji gbe ọhun lowo nla, ko too di pe ọwọ awọn agbofinro tẹ wọn laipẹ yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Edo, D.S.P Edafe Bright, sọ ọ di mimọ fawọn oniroyin lakooko to n ṣafihan awọn ọdaran ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pe otẹẹli kan niluu Onitsha, lawọn ti lọọ fọwọ ofin mu awọn ọdaran naa, tawọn si ba ibọn agbelẹrọ kan atawọn ohun ija oloro miiran lọwọ wọn.
Alukoro ọhun ni, ‘Ni nnkan bii ago mẹjọ arọ kutukutu ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, yii ni Abilekọ Aisha Yusuf to n gbe lagbegbe Abraka, niluu Asaba, waa fẹjọ sun ni teṣan awọn ọlọpaa pe oun n wa ọmọ oun kan torukọ rẹ n jẹ Abubakar Atiku, ọmọọdun mẹta. Mohammed Isah, ẹni ọdun marunlelọgbọn, lo fẹsun kan pe o ji oun lọmọ gbe.
Loju-ẹsẹ ni Kọmiṣanna ọlọpaa, C.P Wale Abbas, ti paṣẹ fun DPO agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ pe, ko ṣewadii lori ọrọ ọhun.
Iwadii ti Ti DPO, C.S.P Apu Torekeregha, ṣe lọwọ fi tẹ awọn ọdaran naa, ti wọn si fọwọ ofin mu Mohammed Isah atawọn ọdaran kan lọja Abraka, nijọba ibilẹ Oshimili South, nipinlẹ naa.
Isah yii lo jẹwọ, to si mu awọn ọlọpaa de ọdọ awọn yooku rẹ, ti wọn si fọwọ ofin mu gbogbo wọn pata.
Alukoro ni ninu iwadii awọn lawọn ti ri i pe, ogbologboo ajinigbe lawọn tawọn fọwọ ofin mu naa, to jẹ pe ṣe ni wọn maa n ji awọn ọmọde gbe lagbegbe ohun, ti wọn yoo si lọọ ta wọn silẹ ajeji lowo nla.
Edafe ni ilu Onitsha, nipinlẹ Anambra, lawọn ti lọọ gba ọmọ tawọn ọdaran naa ji gbe gba pada wa sile.
O ni, ‘Otẹẹli kan bayii to wa ni Onitsha, nipinlẹ Anambra, la ti lọọ gba Atiku lọwọ Ọgbẹni Suleiman Mohammed, ẹni ti wọn gbe ọmọ naa fun pe ko tọju rẹ. A ti fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọdaran yii patapata, wọn si n ran wa lọwọ ninu iwadii wa bayii
Bakan naa la ti da Atiku pada fun iya rẹ.