Laide Bakare ṣayẹyẹ ọjọọbi alarinrin fun Toyọsi Adesanya

Faith Adebọla

Awọn agba bọ, wọn ni ‘aaye la a jogun ọrẹ,’ ati pe eeyan bo ni lara ju aṣọ lọ. Owe yii lo wọ ayẹyẹ alarinrin kan to waye niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, laṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, nibi ti gbajugbaja oṣere-binrin to rẹwa bii eegbin nni, Laide Bakare, ti file pọnti, to fọna roka lati ṣapọnle ọrẹ rẹ lagbo tiata, Toyọsi Adesanya.

Ki aago mẹrin irọlẹ ti wọn fi eto ọhun si too lu lawọn alejo pataki pataki ti n de si gbọngan apejẹ kan to wa ninu loke pẹtẹẹsi ileetura The Grid Lagos, lagbegbe Ọpẹbi, n’Ikẹja.

Nnkan bii aago marun-un ni Toyọsi Adesanya de ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, aṣọ funfun kinniwin kan ti wọn fi goolu ṣẹṣọ si lo wọ, bẹẹ ni Laide Bakare yọ lẹyin rẹ, pẹlu aṣọ igbalode alawọ pupa rẹsurẹsu to joju ni gbese kan bayii, to si gbe ẹwa oṣere yii jade daadaa.

Nigba ti ayẹyẹ naa bẹrẹ, Oniwaasi ẹsin Musulumi kan Sheik Authentic Solaty, lo sọrọ iwuri nipa ayẹyẹ naa, o gboṣuba fun Laide Bakare, pe bawọn ọrẹ to ṣee mu yangan ṣe maa n baṣiiri ọrẹ wọn, ti wọn maa n ṣapọnle ọrẹ wọn lo ṣe yii, bẹẹ lo ṣadura fun ọlọjọọbi, Toyọsi Adesanya, ati ọkọ rẹ, tawọn mẹtẹẹta jọọ jokoo papọ.

Lẹyin naa ni ijo ati ariya bẹrẹ ni wẹlẹmu, ti ọlọjọọbi paarọ aṣọ si ti elere idaraya buluu kan bayii, idunnu oun ati Laide si legba kan bi wọn ṣe n ran bii okoto lagbo.

Ọpọ awọn onitiata ni wọn pesẹ sibi ayẹyẹ naa, ti koowa wọn si sọrọ daadaa nipa ọlọjọọbi yii, ati ọrẹminu rẹ, Laide.

Lara wọn ni Ayọ Badmus, Bisi Ibidapọ-Obe, Ṣọla Kosọkọ, Esther Kalejaiye ‘Ọmọ jọ yibo’, Bimbọ Thomas, Fathia Balogun, Folukẹ Daramọla-Salakọ, Funṣọ Adeolu, Ayọ Ewebiyi, oṣere-binrin akewi to tun n kọrin, ọga ileeṣẹ Corporate Pictures, Alhaji Abdullahi Abdulrasaq, atawọn mi-in. Ọba alade kan tun wa nikalẹ nibi ayẹyẹ naa, Ọba Oloyede Akinghare tiluu Okeluṣẹ.

Laide Bakare, to ba ALAROYE sọrọ nibi ayẹyẹ naa sọ pe idi toun fi ṣenawo toun ṣe yii ki i ṣe ti ṣe-ka-ri-mi rara, ṣugbọn oun fẹ kawọn eeyan, paapaa awọn oṣere ẹlẹgbẹ oun mọ pe ko digba ti ọkan lara awọn ba ku kawọn too bẹrẹ si i dawo lati ṣẹyẹ fun tọhun, o ni loju aye awọn onitiata lo ti yẹ kawọn maa pọn ara wọn le, kawọn si ṣeranwọ ati iwuri fun ara awọn.

Leave a Reply