Adewale Adeoye
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ki i ṣe ọjọ kan tawọn ara agbegbe Dorayi, nijọba ibilẹ Zaria, maa tete gbagbe nigbesi aye wọn.
Ko sohun meji ti eyi maa fi ri bẹẹ ju pe ọjọ ọhun lawọn agbebọn kan ti wọn pọ daadaa ya wọnu ilu kekere naa, ti wọn si pa olori ẹya kan ti wọn n pe ni Kewaye-Zazzzau, Alhaji Shuaibu Mohammed atawọn ọmọ rẹ mẹrẹẹrin lẹẹkan ṣoṣo.
Awọn ọmọ olori ilu ọhun ti wọn pa danu ni: Musa Shuaibu, Abubakar Shuaibu, Adamu Shuaibu ati Ibrahim Haruna Shuaibu.
Yatọ sawọn eeyan ọhun tawọn agbebọn yii pa danu, ALAROYE gbọ pe wọn tun ji awọn maaluu to le ni ọgọrun-un to jẹ tawọn araalu naa lọ.
Iṣẹlẹ ọhun ti mu kinu ilu naa da paro-parọ bayii, ọpọ awọn araalu naa ni wọn ti n ko ẹru wọn jade nitori wọn ko mọgba tawọn agbebọn naa tun le pada waa kogun ja awọn. Won ni niwọn igba ti wọn ti pa olori ilu naa ati awọn mọlẹbi rẹ danu bii ẹran, ẹmi awọn tawọn je araalu lasan ko de rara niyẹn.
Ọkan lara awọn iyawo oloogbe naa, Abilekọ Malama Halima Shuaibu, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn de sinu ọgba ile awọn, ti wọn si lọ taarata sinu ibi ti Shuaibu wa, wọn wọ ọ jade sita gbangba, wọn si yinbọn fun un lẹẹmeji, to si ku loju-ẹsẹ.
Halima ni, ‘Afi bii ẹni pe ogun de ni, awọn agbebọn naa pọ gidi, bẹẹ ni wọn bẹrẹ si i wọnu awọn yara kọọkan lọ, ti wọn si n mu awọn ọmọ oloogbe yii jade sita. Gbogbo awọn ọmọ mẹrẹerin ti Shuaibu bi ti wọn jẹ ọkunrin ni wọn pa pata. Oju mi ko gba a mọ nigba ti wọn mu ẹni kẹrin jade, ti wọn si yinbọn foun naa lagbari. Mi o mọ ohun ti Shuaibu ṣe fawọn ọdaran naa, ki i ja laarin ilu, jẹẹjẹ rẹ lo maa n lọ, o si da mi loju pe ohun to ṣẹlẹ naa ki i ṣoju lasan rara, wọn mọ ọn mọ pa idilẹ Shuaibu run ni, ki oye to jẹ le bọ sọwọ ẹlomi-in.
Ọmọ Oloogbe Shuaibu kan ṣoṣo ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji ọhun, Abdulrahman, ni bi Ọlorun ṣe ko oun yọ paapaa ṣi n ya oun lẹnu ni, ati pe bi oun paapaa ba wa ninu ile lakooko ọhun ni, o ṣee ṣe ki wọn pa oun naa danu bi wọn ti pa awọn ẹgbọn oun yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zaria, D.S.P Muhammad Jalig, ti sọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa, o ni awọn yoo bẹrẹ iṣe abẹnu nipa ọrọ awọn agbebọn naa, ti ọwọ yoo si tẹ wọn laipẹ yii.