Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, nipinlẹ Ọṣun, ti kede yiyọ alaga wọn, Ọmọọba Bello Adebayọ, lori ẹsun hihuwa ọdalẹ ninu ẹgbẹ, ati ṣiṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu.
Nibi ipade oniroyin kan to waye niluu Oṣogbo, ni awọn oloye ẹgbẹ Labour ni Ward 12, ijọba ibilẹ Oṣogbo, ti Adebayọ ti wa, ti kọkọ kede pe awọn yọ ọkunrin naa nibaamu pẹlu abala kọkandinlogun isọri keji, kẹta, kẹrin ati ikarun-un iwe ofin ẹgbẹ naa.
Bakan naa ni awọn alaga ẹgbẹ yii kaakiri ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ọṣun, ti Raheem Taiwo Ojo, ko sodi sọ pe Adebayọ ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn mọ niwọn igba ti awọn oloye ẹgbẹ ni wọọdu to ti wa ti da a duro.
Wọn ni awọn nigbagbọ ninu adele-alaga ẹgbẹ naa tuntun, Oloye Suzan Ojo, bẹẹ ni wọn ṣeleri atilẹyin fun oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ ọhun lorileede yii, Barisita Akingbade Oyelekan.
Ninu ọrọ tirẹ, Adele-alaga ẹgbẹ, Suzan Ojo, ṣalaye pe miliọnu lọna mẹrin Naira ni oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ naa, Peter Obi, gbe kalẹ fun eto ipolongo to waa ṣe nipinlẹ Ọṣun, ṣe ni Adebayọ ṣe owo naa baṣubaṣu.
O sọ siwaju pe lasiko idibo apapọ to waye kọja, miliọnu lọna ọgbọn Naira ni awọn alakooso apapọ ẹgbẹ naa fi ranṣẹ si Adebayọ lati pin fun awọn aṣoju ẹgbẹ nile idibo kọọkan, ṣugbọn owo naa ko ni akanti donii.
Latari gbogbo awọn ẹsun wọnyi, o ke sawọn agbofinro lati fi pampẹ ofin mu Adebayọ nibikibi to ba ti fi ara rẹ han gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun, nitori ẹgbẹ ko mọ ọn ri, o si ke si awọn araalu lati ma ṣe ni nnkan an ṣe pẹlu rẹ lorukọ ẹgbẹ LP.
Nigba to n fesi si awọn ẹsun naa, Bello Adebayọ ṣalaye pe ko si oloye ẹgbẹ kankan ni Ward 12 lọwọlọwọ to le yọ oun, o ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-un Naira pere ni owo ti Oloye Akin Ọṣuntokun fi ranṣẹ soun, ẹri si wa nilẹ fun ẹnikẹni to ba fẹẹ ri i.