Ijọba mi yoo faaye gba awọn oniṣowo gbogbo nilẹ yii, ki okoowo wọn le burẹkẹ si i- Tinubu

Adewale Adeoye

Olori orile-ede yii, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, ti ṣeleri ayọ fun gbogbo awọn oniṣowo gbogbo lagbaaye pe ki wọn ma foya rara lati waa da ileeṣẹ silẹ lorileede wa Naijiria, nitori pe gbogbo ohun ti wọn nilo pata lati jẹ ki okoowo wọn gberu si i bi wọn ba waa daṣẹ silẹ lorileede wa Naijiria loun maa ṣe fun wọn.

Tinubu sọrọ ọhun di mímọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lakooko to n gba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ‘Bharti Airtel’, Ọgbẹni Sunil Bharti Mittal ati ti ‘Africa Group Chief Executive,’ Ọgbẹni Ṣegun Ogunsanya, lalejo lọfiisi rẹ niluu Abuja

O ni oun ranti ipa pataki toun ko lakooko toun wa nipo gomina ipinlẹ Eko lati jẹ ki ileeṣẹ Econet, to ti yi oruko pada si Airtel bayii fẹsẹ mulẹ daadaa lorileede wa Naijiria nigba naa lọhun-un. Bakan naa lo gboṣuba fun bi awọn alakooso ileeṣẹ naa ṣe n ṣeto ohun gbogbo, ti ileeṣẹ ọhun  si n tẹsiwaju latigba naa.

Tinubu ni, ‘Mo mọ ipilẹ Airtel daadaa lorileede wa Naijiria, nigba ti mo fi wa nipo gomina ipinlẹ Eko, mo wa lara awọn to ja fita-fita lati jẹ ki ileeṣẹ Econet nigba naa lọhun-un fẹsẹ mulẹ daadaa lorileede wa, kohun gbogbo le lọ deede nilẹ wa, mọ mọ pe imọ ẹrọ ti ilẹ India faaye gba wa lara ohun to sọ wọn di aṣaaju ninu ohun gbogbo lapa ọdọ wọn lọhun-un. Awa paapaa maa wo awokọṣe ohun to ba daa bayii.’’

Bakan naa lo tun nawọ ibaṣepọ si wọn, eyi to ni yoo ran eto ọrọ-aje orileede Naijiria lọwọ lati fopin si iṣẹ ati oṣi to n koju awọn ọmọ ilẹ wa bayii.

Nigba to n fẹmi imoore han si i, Ọgbẹni Mittal dupẹ gidi lọwọ olori orileede wa,

bakan naa lo gboṣuba nla fun un lori awọn igbesẹ to ti gbe latigba to ti gba ijọba orile-ede Naijiria bayii, eyi to ni o ti da ogo orile-ede yii pada siwaju laarin awọn orilẹ-ede gbogbo lagbaaye.

Bakan na lo lu Tinubu lọgọ ẹnu lori bo ti ṣe yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu ati ọgbọn to da lori owo dọla

O ni pẹlu awọn igbesẹ pataki wọnyi, ko ni i pẹ rara ti ọpọ awọn oniṣowo lagbaaye yoo fi maa wa sorileede Naijiria lati waa daṣẹ silẹ.

Bakan naa ni Ogunsanya rọ ijọba apapọ pe ki wọn fọwọ lile mu ọrọ awọn janduku gbogbo to jẹ pe awọn irinṣẹ awọn ni wọn maa n bajẹ nigba gbogbo.

 

Leave a Reply