Nitori ibi ọmọ tuntun to dawati, oṣiṣẹ eto ilera mẹta ha sọwọ ọlọpaa l’Emure-Ile

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera mẹta ni wọn ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo latari ibi ọmọ tuntun kan to deedee dawati nile-iwosan ti wọn ti n ṣiṣẹ ni Emure-Ile, n’ijọba ibilẹ Ọwọ.

ALAROYE gbọ pe awọn mẹtẹẹta ọhun ti wọn jẹ oṣiṣẹ eleto ilera nile-iwosan alabọọde to wa niluu Emure-Ile ni wọn fẹsun kan pe wọn ji ibi ọdọmọde-bìnrin naa ni kete ti iya rẹ bi i tan lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 ta a wa yii.

Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo ti sọ awọn obi ọmọ tuntun naa, iyẹn Tunde Ijanusi, ẹni ọdun mẹtalelogun, to jẹ baba rẹ ati iya rẹ, Joy John, ti ko ti i ju bi ọmọ ọdun mọkandinlogun lọ sinu ibanujẹ latigba naa.

Ninu ọrọ Abilekọ Funmilayọ Ijanusi to jẹ iya baba ọmọ, o ni awawi ti ko ṣee gbọ leti lawọn oṣiṣẹ naa n sọ fawọn nigba tawọn n beere bi ibi ọmọ awọn ṣe rin lọwọ wọn.

O ni ohun ti wọn n sọ ni pe aja kan lo deedee ja wọ ọsibitu awọn lojiji, to si ji i gbe sa lọ, ti awọn ko si ri ohunkohun ṣe si i.

O ni ọrọ ibi ọmọ tuntun ki i ṣe nnkan kekere ninu ẹbi awọn, nitori igbagbọ awọn ni pe ibi-ọmọ ni nnkan an ṣe pẹlu bi ọjọ ọla ọmọ yoo ṣe ri.

Funmilayọ ni loootọ lawọn to jẹ alábòójútó ile-iwosan naa ti n bẹbẹ, ti wọn si n parọwa pe ki awọn mẹnu kuro lori rẹ, ṣugbọn iṣẹlẹ ọhun ki i ṣohun ti awọn le gba ko lọ bẹẹ lai jẹ ki awọn mọ ibi ti ibi ọmọ awọn wọlẹ si.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn afurasi mẹta naa ti wa nikaawọ awọn, ti awọn si n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Ọdunlami ni lara awọn ti awọn ti fi pampẹ ofin gbe ni nọọsi kan, oluranlọwọ eleto ilera kan ati ẹṣọ alaabo kan to n ṣiṣẹ ni ọsibitu alabọọde ọhun.

Ẹgbẹ awọn nọọsi nipinlẹ Ondo naa ti sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun ninu atẹjade kan ti Kẹhinde Olomiye ti i ṣe alaga wọn fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii.

Olomiye ni ko si ọmọ ẹgbẹ awọn kankan ninu awọn mẹtẹẹta tọwọ awọn agbofinro ti tẹ lori ẹsun ibi ọmọ ti wọn ji gbe.

 

Leave a Reply