Ọmọọya meji ti rewele o, tẹgbọn-taburo dero ẹwọn l’Ekiti

Faith Adebọla

Loootọ lawọn Yooba maa n powe pe ọmọọya meji ki i r’ewele, amọ owe yii ko ṣiṣẹ ninu ọrọ to ṣẹlẹ sawọn ọmọọya meji kan, Sunday Arowoṣoki, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ati aburo rẹ, Gbọlaga Arowoṣoki, ẹni ọdun mẹtalelogun, awọn mejeeji ladajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan dajọ fun pe ki ọkọọkan wọn lọọ fẹwọn ọsu mẹẹẹdogun, ti i ṣe ọdun kan ati oṣu mẹta mẹta jura, fun pe wọn jẹbi ẹsun mimọ-ọn-mọ ba dukia iyawo bọọda wọn kan jẹ, ti wọn tun ṣakọlu sonitọhun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii, ni idajọ naa waye nile-ẹjọ Majisreeti to fikalẹ si ilu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Wọn ni niṣe lawọn mejeeji dunrun mọ Abilekọ Racheal Arowoṣoki, obinrin opo kan to jẹ iyawo ẹgbọn wọn to ti doloogbepe lajẹ ni, ki i ṣẹni teeyan n sun mọ rara, wọn ni ẹmi buruku wa lara ẹ, ko si lero rere sawọn, eyi lo mu ki wọn dẹyẹ si i.

Ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn, nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni wọn lawọn ọdaran yii lọọ huwa arufin ọhun ni Ayegunlẹ Ekiti, nijọba ibilẹ Ijero, nipinlẹ Ekiti, wọn ṣakọlu si iyawo ẹgbọn wọn pẹlu oniruuru nnkan ija oloro, bi wọn ṣe ṣe obinrin naa leṣe ni wọn tun gbọn ṣọọbu to ti n taja yẹbẹyẹbẹ, wọn ba dukia rẹ jẹ, ni wọn ba ba tiwọn lọ.

Ẹyin eyi lawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin gbe wọn, nigba ti obinrin naa fẹjọ wọn sun ni teṣan, lọrọ ba ṣe bii ere bii ere di ti kootu.

Lara ẹsun ti Agbefọba, Inspẹkitọ Elijah Adejare, ka si wọn lẹsẹ, ti wọn si jẹbi rẹ ni igbimọ-pọ lati huwa aidaa, ṣiṣe akọlu si ọmọlakeji ẹni, mimọ-ọn-mọ ba dukia ẹlomi-in jẹ, ati idunkooko mọ ni.

Wọn lawọn ẹsun yii ta ko isọri okoolenirinwo o lekan, isọri marunlelọgọsan-an ati isọri ọtalelọọọdunrun din mẹfa, ninu iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2021 ti ipinlẹ Ekiti n lo.

Onidaajọ Ọlatọmiwa Daramọla to gbe idajọ rẹ kalẹ lẹyin tawọn olujẹjọ mejeeji ti gba pe awọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn sọ pe awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ọhun ti pọ to lati da wọn lẹbi, lo ba ni ki tẹgbọn-taburo naa lọọ faṣọ pempe roko ọba fọdun kan aabọ lọtọọtọ, ki wọn le mọ pe iwa buruku ni lati ba dukia ẹni ẹlẹni jẹ.

Leave a Reply