Adewale Adeoye
Onidaajọ Jane Young-Daniel, ti ile-ejọ Majisireeti kan to wa niluu Aba, nipinlẹ Anambra, ti ni ki wọn lọọ ju Pasitọ Chukwuemeka Orji, oludasilẹ ijọ Ọlọrun kan ti wọn n pe ni ‘Assemblies Of God Church’, to wa lagbegbe Ngaw, niluu Aba sẹwọn.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ba ọmọọdọ rẹ kan ti ko ju ọmọ ọdun mẹtala lọ lo pọ.
ALAROYE gbọ pe ohun to ṣe rọrun fun iranṣẹ Ọlọrun naa lati maa ba ọmọ naa sun nigba gbogbo ni pe ile pasitọ ọhun ni ọmọ naa n gbe, awọn obi rẹ si n lọ si ẹka ṣọọṣi naa kan to wa niluu ọhun.
Pasitọ Chukwuemeka ati iyawo rẹ gba lati maa ṣetọju ọmọ ọhun nigba tawọn obi ọmọ naa ko lagbara lati ran an lọ sileewe. Anfaani yii ni ọkunrin to pera ẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun yii lo to fi maa n ba ọmọ naa sun nigba gbogbo.Nigba ti ọmọ ọhun ko si nifẹẹ sohun ti pasitọ yii n ṣe pẹlu rẹ mọ lo ba sọ fun iyawo iranṣẹ Olọrun naa. Oju-ẹsẹ ni iyawo ọkunrin yii beere ohun ti ọmọ yii sọ lọwọ rẹ, ṣugbọn ṣugbọn ti pasitọ sọ pe ko soootọ kankan ninu ẹsun tọmọ naa fi kan oun niwaju iyawo rẹ yii.
Eyi lo mu ki ọkunrin yii bẹrẹ si i kanra mọ ọmọ yii, to si n dukooko mọ ọn pe bo ba gbiyanju lati sọ ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji yii fẹnikẹni, oun yoo le e jade kuro ninu ọgba ile oun ni. Iṣẹlẹ yii lo mu ki inu ọmọ naa bajẹ, to si n wa ẹkun mu nigba gbogbo.
Nibi to ti n sunkun lọwọ ni ọkan lara awọn tiṣa rẹ ti ri i, ti wọn si beere ọrọ lọwọ rẹ. Lẹyin tọmọ yii ṣalaye gbogbo ohun toju rẹ n ri lọwọ baba agbaaya yii, ni awọn olukọ naa lọọ fọrọ ọhun to awọn alaṣẹ ijọba agbegbe ọhun leti.
Lakooko ti igbẹjọ n lọ lọwọ lọmọ naa tu gbogbo aṣiri ikọkọ to wa laarin oun pẹlu Chukwuemeka yii sita, ti ẹnu si ya gbogbo awọn ti wọn wa lori ijokoo lọjọ naa.
Ọmọ naa sọ pe, ‘‘Ko pẹ rara ti mo dele Pasitọ Chukwuemeka ni wọn ti n ba mi sun, mo maa n sọ fun wọn pe mi o nifẹẹ s’ohun ti wọn n ṣe pẹlu mi yii, nigba to maa fi dori ẹlẹẹkẹta ni mo sọ fun iyawo wọn, Abilekọ Mercy, iyawo wọn si beere ọrọ naa lọwọ wọn niṣoju mi, ṣe ni wọn ta ko mi pe ko sohun to jọ bẹẹ laarin awa mejeeji rara.
Bi iyawo wọn ti jade nile tan bayii niwọn tun kilọ fun mi pe mi o gbọdọ sọ ohun to wa laarin awa mejeeji fun ẹda alaaye Kankan, pe ti mo ba sọ, awọn yoo da mi pada siluu nibi tawọn obi mi n gbe, lẹyin naa ni wọn ṣẹṣẹ tun tẹra mọ ohun ti wọn n ṣe yii.
‘‘Igba kan tiẹ wa ti mo n ṣe nnkan oṣu lọwọ, iyẹn lọjọ Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lẹyin ti iyawo wọn jade nile to lọ sọja lati lọọ ra nnkan wa sile, ti pasitọ si fẹẹ fipa ba mi sun, nigba ti wọn ri i pe loootọ ni mo n ṣe nnkan oṣu mi lọwọ ni wọn ba sọ pe, ki n maa la ‘kinni’ wọn. Eyi ṣajoji si mi gidi, mo gba lati la a, ṣugbọn inu mi ko dun rara.
‘‘Nigba ti mo deleewe mi ni awọn olukọ mi kan ti wọn ri i pe inu mi ko dun beere ohun to n ṣe mi lọwọ mi, ti mo si sọ ohun ti Pasitọ Chukwuemeka n ṣe fun mi’’.
Gbogbo ẹsun ti ọmọ naa fi kan iranṣẹ Ọlọrun yii pata lo ni ko si ootọ kankan nibẹ rara, to si rawọ ẹbẹ si adajọ naa pe oun ko jẹbi.
Nile-ejọ naa ni adajọ ti pe Abilekọ Mercy ti i ṣe iyawo pasitọ yii lati beere lọwọ rẹ boya o ti figba kan gbọ nipa ẹsun ti ọmọ naa fi kan ọkọ rẹ. Obinrin yii kọkọ fẹẹ parọ lori foonu nigba ti ko ri ẹni to n ba a sọrọ soju, ṣugbọn o pada sọ nigbẹyin pe loootọ lọmọ ọhun sọ foun ri pe ọkọ oun n b’oun sun.
Ọlọpaa olupẹjọ, Abilekọ Mary Udoji, to foju ọkunrin yii bale-ẹjọ sọ pe ki wọn ma ṣe gba beeli rẹ rara, nitori o ṣee ṣe ko maa dunkooko mọ ọmọ ọhun nita.
Eyi ni adajọ fi paṣẹ pe ki wọn lọọ ju u sọgba ẹwọn titi digba ti igbejọ yoo fi waye nipa rẹ.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun yii