Irọ ni, ijọba wa ko ti i fowo kun owo-oṣu oṣiṣẹ- Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ta ko iroyin to n ja ran-in ran-in lori ẹrọ ayelujara pe ijọba ti ṣafikun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa.

Makinde sọrọ yii ninu atẹjade ti Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Pasitọ Sulaiman Ọlanrewaju, fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

O ni, “Irọ to jinna soootọ ni iroyin kan to n lọ lori ẹrọ ayelujara pe a ti fẹẹ fowo kun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ.

“Loootọ la ti n ṣiṣẹ lori afikun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ, ṣugbọn ki i ṣe bii iru eyi ti awọn kan n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara”.

 

Leave a Reply