Adewale Adeoye
Awọn ọdẹ mẹrin kan, Habila Anbeyi, ẹni ọdun mẹrindilogun, Naruka Sababou, ẹni ọdun mọkandinlogun, Audi Ali, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ati John Danladi, ẹni ọgbọn ọdun, ni adajọ ile-ẹjọ kan ti wọn n pe ni ‘Grade1 Area Court,’ to wa niluu Kabusa, l’Abuja, Onidaajọ Abubakar Sadiq, ni ki ẹnikọọkan wọn lọọ ṣewọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara gẹgẹ bi ijiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe.
ALAROYE gbọ pe ileeṣẹ kan to n pese aabo fawọn araalu, eyi ti wọn n pe ni ‘Falzal Security Company’, to wa lagbegbe Wuse, niluu Abuja, lawọn mẹrẹẹrin ọhun ti n ṣiṣẹ. Niṣe ni wọn gbimọ pọ lati ji epo diisu ileeṣẹ naa ta fun awọn araata.
Ọlọpaa olupẹjọ, Ọgbẹni S.O Osho, to foju awọn ọdaran naa han nile-ẹjọ sọ pe Akaaza Samuel, to jẹ ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ ọhun lo lọọ fọrọ awọn odaran naa to ọlọpaa agbegbe Asokoro, niluu Abuja leti lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Agbefọba sọ pe, “Ẹyin mẹrẹẹrin yii, ẹ gbimọ-pọ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, tẹ ẹ si ji epo diisu ileeṣẹ tẹ ẹ ti n ṣiṣẹ. Igba lita (200lt) ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira lẹ ji gbe. Loju-ẹsẹ tẹ ẹ ti ji epo ọhun tan lẹ ti ta a fun ọkunrin kan forukọ rẹ n jẹ Lawal lowo pọọku, ko too di pe, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ yin.
“Loootọ, ẹ ti jẹwọ fawọn agbofinro lasiko ti wọn ni beere ọrọ lọwọ yin, ṣugbọn ijiya nla wa fun ohun tẹ ẹ ṣe yii labẹ ofin ilu yii”.
Bi ọlọpaa olupẹjọ ti ka awọn ẹṣẹ tawọn mẹrẹẹrin ṣẹ ṣi wọn lẹsẹ tan ni awọn paapaa ti gba pe loootọ lawọn jẹbi esun iwa ọdaran gbogbo ti wọn fi kan won pata, ti wọn si rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ naa pe ko ṣiju aanu wo awọn lori ọrọ to wa niwaju rẹ ọhun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Sadiq, ni ki ẹnikọọkan wọn lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira gẹgẹ bii owo itanran.
Bakan naa ni adajọ ni ki ẹnikọọkan wọn tun san ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn Naira fun ileeṣẹ ti wọn ja lole naa gẹgẹ bíi owo gba-ma-binu fun dukia rẹ ti wọn ji.
O ni bi wọn ba kọ lati sanwo ọhun, oun yoo fi oṣu meji kun ọjọ ti wọn maa lo lọgba ẹwọn.