Faith Adebọla
Yooba bọ, wọn ni ‘ba a ti ṣe la a wi, ẹnikan ki i yan ana ẹni lodi’, amọ owe yii ko ṣiṣẹ lọdọ ọkọọyawo kan ti wọn porukọ ẹ ni Kabiru Muhammad. Ki i ṣe p’oun yan ana ẹ lodi nikan ni, niṣe lo kuku wọ gbogbo wọn rele-ẹjọ, o ni niṣe lawọn ana ohun sopanpa, ti wọn waa fagidi mu ọmọ wọn, iyẹn iyawo oun, kuro lọọdẹ oun nigba toun ko si nile, bẹẹ oun o jẹ wọn lowo, oun o si fẹyawo naa lọfẹẹ, wọn ko si gba iyọnda lọwọ oun ki wọn too ṣe ohun ti wọn ṣe yii.
Ile-ẹjọ Sharia kan to wa nigbori ilu Kano, lagbegbe Hotoro Masallachi, ni ọkunrin naa wọ awọn mọlẹbi iyawo ẹ mẹta lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Orukọ awọn ana Kabiru ti wọn n kawọ pọnyin rojọ lọwọ ọhun ni Ali Dan Abba, Hadiza Dan Abba ati Haruna Bala Gangwauro.
Amọ, iyawo ọkunrin yii ṣalaye ni kootu naa lasiko igbẹjọ pe ọrọ ko ri bẹẹ o, ki i ṣe pe awọn eeyan oun waa fipa mu oun kuro lọọdẹ ọkọ oun o, o ni funra oun loun lọ sile ẹgbọn oun obinrin kan latari bi ọkọ oun ko ṣe tọju oun, ti ko si bikita fun oun.
Obinrin naa sọ fun adajọ pe: “Ẹ ma da ọkọ mi lohun jare, emi ni mo fẹsẹ ara mi rin lọ sọdọ ẹgbọn mi obinrin, ko sẹni to fipa mu mi. Ara mi ko ya fungba pipẹ bayii, ọkọ mi ko gbe mi lọ sọsibitu ki n le gba itọju, niṣe lo n foni-doni-in fọla-dọla fun mi, ko bikita fun iwalaaye mi pẹẹ, tori ẹ ni mo ṣe lọ sọdọ aunti mi nijọba ibilẹ Dambatta, ki wọn le tọju mi.”
Ṣugbọn olupẹjọ ni ko ri bẹẹ, awọn ana oun fẹẹ mọ-ọn-mọ fọwọ ọla gba oun loju ni, o ni niṣe ni wọn fagbo feegun, ti wọn kọ ti wọn ko ju okun ẹ silẹ, tori o ti pẹ ti wọn ti n halẹ mọ oun lori ọrọ iyawo oun yii pe awọn maa waa mu ọmọ awọn toun o ba tọju ẹ.
Adajọ kootu naa, Mallam Nasir Muhammad Ahmad, yiri ọrọ naa wo, lo ba paṣẹ pe ki wọn yọnda fun obinrin yii lati maa lọ sileewosan na, tori boun ṣe n wo o yii, o nilo itọju iṣegun gidi.
O faaye beeli silẹ fawọn ana Kabiru mẹtẹẹta pe ki wọn ṣi maa lọ sile wọn na, nigba ti ara iyawo naa ba ti mokun daadaa, igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ siwaju.