Aye ti bajẹ o! Ọmọọdun mẹtala wa ninu ikọ adigunjale

Faith Adebọla

Ki lo le sun ọmọọdun mẹtala pere, to yẹ ko wa laarin awọn ẹlẹgbẹ ẹ nileewe, darapọ mọ ikọ adigunjale ti wọn n han ilu leemọ? Ibeere yii lawọn ti wọn ri fotọ ọmọọdun mẹtala kan, Shuaibu Sudais, n beere tiyanu-tiyanu lasiko ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, SP Suleiman Nguroje, fi atẹjade ati fọto awọn afurasi ọdaran marun-un kan tọwọ wọn ṣẹṣẹ ba lede. O ni iṣẹ adigunjale pọnbele lawọn eleyii n ṣe, wọn si ti wa nidii iṣẹ naa, ilẹ ti ta si i.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, ni Nguroje fọrọ ọhun lede fawọn oniroyin, o lo ti pẹ tawọn ti n gburoo iṣẹ laabi awọn adigunjale yii, bi wọn ṣe n lọ kaakiri, to jẹ igbe ẹkun, ati adanu ni wọn n fi silẹ fawọn ti wọn ba ba lalejo laarin ilu Adamawa, awọn ọlọpaa si ti n wa wọn, ṣugbọn wọn o ri wọn mu bọrọ.

Orukọ ati ọjọ ori awọn maraarun ni Yusuf Bashir, ọmọọdun mejidinlogun, lsa Muhammed ati Muhammed Hassan tawọn mejeeji jẹ ẹni ogun ọdun, awọn si ni wọn dagba ju awọn yooku lọ, Ayọ Morounfade, ọmọ ọdun mejidinlogun, Shuaibu Sudais, lo si kere ju laaarin wọn, ọmọọdun mẹtala ni.

Alukoro ni ohun to jọ ni loju pupọ ninu iṣẹlẹ yii ni bo ṣe jẹ pe ko seyii ti ọjọ-ori ẹ kọja ogun ọdun laarin ikọ adigunjale yii, o tumọ si pe ataarọ ọjọ awọn afurasi yii ni wọn ti  ba iwa ọdaran mulẹ bii ẹgbẹ iṣu ni tiwọn.

O ni iwadii tawọn ṣe fihan pe ọpọ ṣọọbu ati ile ti wọn fọ lẹnu aipẹ yii ko ṣẹyin awọn ọmọ ọhun, niṣe ni wọn maa n foru boju ja ilẹkun ṣọọbu oniṣọọbu, wọn aa si ko wọn lẹru lọ.

Alukoro ni lara awọn ẹru ole bẹẹ tawọn ba nikaawọ wọn ẹrọ iranṣọ kan, gẹnẹretọ amunawa nla kan, awọn aṣọ olowo nla ti wọn o ti i ran, foonu rẹpẹrẹ, ada, aayun, atawọn nnkan ija mi-in gbogbo.

O lawọn afurasi yii tun maa n ṣakọlu sawọn eeyan lọna, paapaa awọn ti wọn ba n rin loru.

Ṣa wọn ti fọwọ ofin mu gbogbo wọn, wọn si ti taari wọn si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ Adamawa, fun iwadii to lọọrin nipa wọn, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Afọlabi Babalọla, ṣe paṣẹ.

Wọn ni lẹyin iwadii, igbẹjọ ati idajọ ni yoo tẹle e fawọn afurasi ọdaran wọnyi ni kootu.

Leave a Reply