Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ajọ to n gbogun ti fífi awọn ọmọde ṣowo ẹru nipinle Edo, ‘The Edo State Taskforce Against Human Trafficking,’ ti fọwọ ofin mu awọn tọkọ-taya meji kan, Ọgbeni Anthony Igbinogun, ẹni ọdun mejidinlaaadọta ati iyawo rẹ, Abilekọ Joy Umukoro, ẹni ọdun mejidinlọgbọn.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ta ọmọ oṣu kan ti wọn bi lati fi ra oogun oloro ti wọn maa mu. Igbese ọhun lawọn alaṣẹ ajọ ọhun sọ pe, o lodi sofin ipinlẹ naa patapata, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.
ALAROYE gbọ pe alarina kan, James Precious, lo ṣeto bawọn tọkọ-taya ọhun ṣe ri ọmọ naa ta síluu Porthar-Court, nipinle Rivers, ṣugbọn tọwọ ti tẹ awọn tọkọ-taya ọhun lori iwa ọdaju ti wọn hu yìí. Bẹẹ lawọn ọlọpaa lawọn ṣi n wa Precious to ṣatọna wọn yii. Miliọnu meji din diẹ Naira (N1.7) ni wọn ta ọmọ naa.
Alakooso ajọ ọhun, Abigail Ihonre, ṣalaye fawọn oniroyin niluu Benin-City, lọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pe iwadii tawọn ṣe fi han pe inu oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Joy bimọ naa ko too di pe oun pẹlu ọkọ rẹ gbimọ-pọ lati ta a danu lowo pọọku.
Ọga agba ajọ ọhun sọ pe iwadii tawọn ṣe nipa ọrọ fi han pe awọn tọkọ-taya ọhun ti jingiri ninu lilo egboogi oloro, ṣugbọn nigba ti wọn ko tete ri owo ti wọn maa fi ra iwọnba ti wọn maa mu lasiko to n wu wọn lati mu un ni wọn ta ọmọ ikoko naa.
Ihonre ni igbesẹ buruku lawọn tọkọ-taya naa gbe bi wọn ṣe ta ọmọ wọn yii, ti ijiya tofin to rọ mọ ohun ti wọn ṣe yii jẹ ọdun meje lọgba ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ihonre ni, ‘Iya ọmọ ọhun ti jẹwọ fun wa bo ṣe ta ọmọ rẹ lowo pọọku, a maa foju gbogbo awọn ta a ti mu lori ọrọ naa bale-ẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn yii.