Monisọla Saka
Iṣẹ ikini ku oriire ati ajọyọ lọtun-un losi, lori ayelujara ati lori foonu, ti n wọle tọ gbajugbaja oṣerebinrin ilẹ wa kan, Bimpe Akintunde, tawọn eeyan mọ si Wasila Coded, pẹlu bi obinrin naa ṣe n palẹmọ fun igbeyawo bayii.
Ọrọ ko ni ṣai ri bẹẹ, nitori oniruuru ijakulẹ to ti ba pade latẹyinwa, ati bo ṣe ti da wa lai ni ade lori fun ọpọlọpọ ọdun.
Laaarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni oṣerebinrin yii gbe fọto oruka olowo iyebiye ti ọkunrin naa fi dẹnu ifẹ kọ ọ pe ko waa ṣe iyawo oun sori ayelujara Instagram.
Bo tilẹ jẹ pe obinrin yii ti ṣe abiyamọ ri, ti ọmọ rẹ obinrin ọhun si ti pe ọdun meje bayii, ko sẹni to fi bẹẹ mọ nipa igbeyawo rẹ ati ọkọ to bimọ fun ọhun, bẹẹ ni Wasila Coded.
Nigba ti yoo fi to ọwọ ọsan ọjọ Aiku yii kan naa, Wasila ti gbe fidio oun ati ọkọ rẹ tuntun yii sori ikanni rẹ, ti wọn jọ wọ aṣọ funfun, ti ọkọ si lo ofi alawọ ewe gẹgẹ bii fila, ti iyawo naa si lo iru ofin yii kan naa fun gele. Orin kan to ni i ṣe pẹlu idupẹ pẹlu ohun gbogbo ti wọn ti la kọja ni awọn tọkọ-tiyawo naa n jo si ninu fidio naa. Bi ọkọ ṣe n woju aya ni aya naa n woju ọkọ rẹ pẹlu ifẹ, ti wọn si n lọ mọra wọn, ti wọn n fi ifẹ han sira wọn.
Ti obinrin yii ba mọ pe ọkọ ti yoo pada fẹ oun lo ti n kanlẹkun ori ẹrọ ayelujara oun labẹnu lati bii ọdun mẹfa sẹyin ni, boya ọrọ naa ko ba ti yanju. Gẹgẹ bo ṣe wa loju opo ayelujara rẹ, inu oṣu Kejila, ọdun 2017, ni ọkunrin naa ti kọkọ ṣe ‘ẹ n lẹ nibẹ yẹn’ si Bimpe, bẹẹ lo sọ fun un pe oun nifẹẹ si awọn ere ẹ ati bo ṣe maa n ṣere, amọ ti Wasila Coded ko fun un lesi kankan. Ọdun meji lẹyin naa, iyẹn lọdun 2019, ọkunrin yii tun pada ki i labẹ aṣọ, ti oṣere yii ko si tun ya si i.
Obinrin yii ti sọ ọ nigba kan ri pe awọn ọkunrin ko nifẹẹ obinrin to ba niwa ire, nitori wọn maa n ri iru ẹni bẹẹ bii ewu si igbesi aye wọn ni. O loun mọ ara oun ni oninuure, nitori bẹẹ loun ṣe n duro de igba toun, ti oun yoo pade ẹni to mọ iyi oun. Bimpe sọ siwaju si i pe o wu oun naa lati pada tun di iyawo lọjọ kan, ṣugbọn toun n tẹ ẹ jẹẹjẹ, nitori bẹẹ loun ko si ṣe ṣe e ni girigiri, toun n fara balẹ fun ẹni naa ti Ọlọrun ti pese foun.
Labẹ awọn fọto to gbe sori Instagram rẹ lo ti ṣalaye sibẹ pe ọkunrin to fẹẹ fi oun ṣaya yii ti nifẹẹ oun ṣaaju koun gan-an alara too mọ ọn, bẹẹ lo ṣadura pe ki Ọlọrun ṣe awọn lọrẹẹ ara awọn kalẹ. Bimpe tun gbe ohun adura rẹ soke nitori awọn oninu buruku ẹda, to jẹ pe ero wọn ni ki irinajo tuntun oun yii ja si ẹkun, o ni ko ni i ṣoju ẹni to ba ni ero ibi si igbeyawo tuntun oun ọhun.
O ni, “Lonii, mo n sọ pe bẹẹ ni, mo n sọ pe ma a ṣe, fun ẹni to ti n gba temi latọjọ pipẹ, ẹni to nifẹẹ mi ati gbogbo nnkan ti mo n ṣe, ololufẹ mi tipẹtipẹ, ọkunrin to ti nifẹẹ mi ki n too pade ẹ rara. Inu mi dun, mo si ri ara mi bii ẹni ibukun lati pade ẹ, inu mi dun gidi gan-an lati bẹrẹ irinajo laelae yii pẹlu ẹ. O ni ki n jẹ iyawo oun, mo si ti jẹ ẹ ni oo. Ki Ọlọrun Ọba jẹ ki irinajo yii rọrun fun wa.
Mumcy Hameedah ti rẹni ba lọ o.
Iwọ to o ba ro o pe ẹkun ni yoo gbẹyin rẹ, ko ni i ṣoju rẹ lagbara Ọlọrun Ọba”.
Latigba naa ni awọn ẹbi, ara, ọrẹ, atawọn akẹgbẹ ẹ nidii iṣẹ tiata ti n ranṣẹ ikini ku oriire si i. Awọn bii Jamiu Azeez, Bukunmi Oluwaṣina, Kẹmi Afọlabi, Bimpe Oyebade, Iyabọ Ojo.
Lara awọn mi-in ti wọn tun ki oṣere naa ni Tawa Ajiṣefinni, ẹni to kọ ọ sori ikanni rẹ bayii pe, Wọn ti mu iya ọkọ mi kuro lori igba oooo! Alhamdulilahi, o ṣe Ọlọrun aanu. Ayọ rẹ yoo kalẹ lagbara Ọlọrun. Mo n duro de aṣọ ẹbi oooo.’’
Bakan naa ni Wumi Ajiboye kọ ni tiẹ pe, ‘‘Ku oriire o, Amọkẹ Ade, Ọlọrun yoo fere si ajọṣepọ yin’’.
Bẹẹ ni Funmi Bank-Anthony, to mu bii iya lagbo ile tiata naa tun kanlẹ pe e, to si n rojọ adura le e lori pe Ọlọrun yoo faaye gba a ninu ile to n lọ. O ni a-pẹ-ko-too-jẹun rẹ ko pada jẹ ibajẹ, pe Ọlọrun a maa ba a lọ.