Ọwọ Amọtẹkun tẹ awọn ọmọ ipinlẹ Benue ti wọn n digunjale l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ awọn Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn okunrin meji kan, Joseph Dennis, ọmọ ogun ọdun, ati Friday Agogo, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, lori ẹsun ole jija.

Wọn gba awọn eeyan naa mu lẹyin ti wọn gbowo lọwọ obinrin oniṣowo kan niluu Ila-Ọrangun.

Ọja la gbọ pe obinrin naa ti n bọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ti wọn fi da a lọna lagbegbe Ẹlẹmọ Ogun, loju ọna Ila Ọrangun, ti wọn si gba gbogbo owo ọja to ta lọwọ rẹ, wọn si tun gbiyanju lati fi ọbẹ gun un.

Lẹyin ti ori ko obinrin yii yọ lo lọ si ọfiisi awọn Amọtẹkun lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, o sọ fun wọn nibẹ pe loootọ lawọn afurasi naa da aṣọ boju, ṣugbọn oun mọ ohun (voice) ọkan lara wọn.

Bi awọn Amọtẹkun ṣe bẹrẹ iwadii niyẹn, ko si pẹ ti ọwọ fi tẹ awọn mejeeji, ti wọn si jẹwọ pe lootọ lawọn huwa naa.

Alakoso Amọtẹkun l’Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewinbi, ṣalaye pe awọn eeyan naa tun jẹwọ pe awọn ti n huwa laabi naa tipẹ.

Adewinbi sọ siwaju pe awọn ti fa awọn ọkunrin mejeeji le awọn ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii, o si rọ awọn araalu lati ṣọra nipa awọn agbegbe ti wọn aa maa gba.

 

Leave a Reply