Faith Adebọla
Baale ile ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Alobo Omokhoa, ti n ṣẹju pako bii maaluu to r’ọbẹ bayii lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ Eko. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n fi aṣọ ọlọpaa lu jibiti. Wọn lọkunrin yii ti ṣiṣẹ ọlọpaa ri, o ṣe aṣemaṣe nla kan ni wọn fi le e danu lẹnu iṣẹ, ṣugbọn iwa ti wọn tori ẹ le e ko kuro lara ẹ.
Ikọ ọlọpaa Rapid Response Squad (RRS) l’Ekoo, ni wọn fọwọ ṣinkun ofin mu afurasi ọdaran yii lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa yii, nibi to ti n pe ara ẹ ni Inspẹkitọ ọlọpaa fawọn eeyan, o ni agbofinro gidi loun, o si gbowo lọwọ awọn ti wọn ba bẹ ẹ niṣẹ, awọn ti wọn n foju ọlọpaa tootọ wo o, laimọ pe irọ lo n pa fun wọn, ko figba kan de ipo inspẹkitọ ri lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ko si si lẹnu iṣẹ ọhun mọ, wọn ti le e danu tipẹ.
Ninu alaye ti kọmanda awọn RRS Eko, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ṣe lori ayelujara lori iṣẹlẹ yii, o ni ọkọ ayọkẹlẹ Golf Volkswagen kan, eyi ti wọn ko awọn irin ti wọn fi n kọle sinu rẹ ni ọkunrin yii pẹlu dẹrẹba ọkọ naa jọọ jokoo siwaju ọkọ, o n tẹle ẹru naa lọ sibi iṣẹ ikọle to n lọ lọwọ lagbegbe Ogudu GRA, l’Ọjọta, ti wọn n ko o lọ, lati pese aabo fun wọn lọna.
Ọkọ yii lawọn ọlọpaa RRS da duro, n lafurasi ọdaran yii ba wawọ si wọn, o si ṣe awọn ami kan si wọn pe ki wọn ma ṣe da awọn duro, tori ọkan lara awọn ọlọpaa ẹlẹgbẹ wọn loun i ṣe, Amọ awọn yẹn o gba, wọn da ọkọ naa duro, wọn si ni ki dẹrẹba ati ọlọpaa yii bọọlẹ lati ṣafihan ara wọn ati ibi ti wọn ti ri ẹru ti wọn ko, ki wọn si sọ ibi ti wọn n ko o lọ fawọn.
Bi wọn ṣe n ṣilẹkun ọkọ, eyi ti Akobo iba fi duro ṣalaye ara ẹ, niṣe lo ki ere mọlẹ bii igba ti ekute foju gan-an-ni ologbo, n lawọn RRS naa ba gba fi ya a, wọn si le e mu.
Igba ti wọn mu un lakara tu sepo, wọn beere ibi to ti n ṣiṣẹ ọlọpaa ati ibi to ti ri yunifọọmu ti wọn ran jagbajagba si i lọrun, lo ba ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, ni tododo, ọlọpaa loun tẹlẹ, amọ wọn ti le oun kuro tori awọn ẹsun kan, igba toun o si rọna atijẹun mi-in loun ṣe dọgbọn sọrọ ara oun, oun loun ran yunifọọmu naa, amọ telọ to ba oun ran an ko ran an daadaa bii eyi tijọba ran fawọn agbofinro ni, loun ba kuku n lo bẹẹ.
Wọn ni niṣe lẹnu ya dẹrẹba ti wọn jọ n lọ tẹlẹ, tori Inspẹkitọ ọlọpaa lọkunrin naa pe ara ẹ fun wọn, owo nla lo si gba lọwọ awọn to lẹru pe oun aa ba wọn daabo bo ẹru wọn de ibi ti wọn n ko o lọ, ko si ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ, o jọ pe jibiti to fi n jẹun lẹyin to kuro lẹnu iṣẹ agbofinro niyẹn.
Ṣa Akobo ti balẹ sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n ṣewadii ẹ daadaa lọwọ gẹgẹ bii aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa pa. Wọn lọrọ rẹ ko ni i pẹẹ dewaju adajọ.