Adajọ ti ju adẹrin-in-poṣonu ilẹ wa nni, Trinityguy, sẹwọn o

Ọlawale Ajao, Ibadan

Wọn pe ọrọ naa lowe, o ti laro ninu bayii, pẹlu bi ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ibadan ṣe paṣẹ pe ki wọn maa gbe ọmọkunrin adẹrin-in-poṣonu to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe nni, Abdullahi Mafur Adisa, ti gbogbo eeyan mọ si Trinityguy, lọ sọgba ẹwọn. Adajọ ni ere to n ṣe to fi ro pe oun n dẹrin-in pa awọn eeyan naa lewu gidigidi, wọn ni bii igba teeyan n kọ ọmọde niṣekuṣe ni.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, ni ọmọkunrin naa fara han niwaju Onidaajọ Adetuyibi, nibi to ti n kawọ pọnyin rojọ lori ẹsun lilo ere awada rẹ naa lati kọ ọmọde ni ikọkuukọọ.

Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun ọmọkunrin adẹrin-in-poṣonu naa, Oludare Adebayọ, bẹ adajọ pe ki wọn fun onibaara rẹ ni beeli, ṣugbọn Onidaajọ Adetuyibi ni ko si ohun to jọ ọ. O ni ki wọn lọọ ju Trinityguy ati awọn obi ọmọ to lo ninu awada to ṣe naa sọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ mi-in yoo fi waye lori ọrọ rẹ. O ni ọrọ naa ti de ileeṣẹ eto idajọ, wọn si ti n yiri rẹ wo lọwọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja lọhun-un ni ọmọkunrin naa gbe fidio kan jade, nibi to ti n beere awọn ibeere to ni i ṣe pẹlu ẹya ara agbalagba ọmọde kan, tọmọ naa si n fi ibẹru da a lohun. Bẹẹ lo tun gbe ere awada mi-in jade, eyi to fi ṣẹru ba awọn eeyan kan debii pe niṣe ni wọn fo iganna ile kan lati sa asala fun ẹmi wọn.

Eyi ni Alukoro apapọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, Muyiwa Adejọbi, ri to fi koro oju si awada naa, o ni ohun to ṣe pẹlu ọmọde yii ati awọn gende-kunrin ti wọn n sa kiri pẹlu ọmọbinrin kan to wọ sutana yii ti kuro ni awada, o ni iwa to lodi si ẹtọ awọn eeyan naa, to si lodi sofin ni. Ọkunrin naa ni niṣe lo yẹ ki wọn gbe adẹrin-in-poṣonu yii.

Ko si pẹ rara ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ, fi kede pe awọn n wa ọkunrin alawada yii, wọn ni ko waa fi ara rẹ han ni teṣan ọlọpaa.

Trinityguy, bi wọn ṣe maa n pe ọkunrin yii yọju si wọn lẹyin ọjọ diẹ, afi bi wọn ṣe ni awọn yoo ba a ṣẹjọ fun iwa to hu naa.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii ni wọn gbe e de iwaju Onidaajọ Adetuyibi, to si paṣẹ pe ki wọn lọọ ti i mọle pẹlu awọn obi ọmọ to fi ṣawada naa.

Leave a Reply