Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Uyo, nipinlẹ Akwa-Ibom, ti sọ pe ọdọ awọn ni Ọgbẹni Gabriel Okon Ekpiri, to n gbe laduugbo Ekit Itam Akpan Obong, nijọba ibilẹ Itu, wa bayii, to sì n ran awọn lọwọ ninu iwadii ijinlẹ tawọn n ṣe nipa rẹ.
Wọn ni gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii tan lawọn maa to foju rẹ bale-ẹjọ, ko le jiya ẹṣẹ to ṣẹ gan-an.
ALAROYE gbọ pe, ẹsun pe Ekpiri ta ọmọ rẹ kan to jẹ ọmọọdun mẹsan-an lẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N400,000) ni awọn ọlọpaa fi kan an, ti wọn si sọ pe ofin ilu ọhun fajuro gidigidi sẹni to ba ṣe bẹẹ laarin ilu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Odiko MacDon, to ṣafihan awọn ọdaran gbogbo tọwọ awọn ọlọpaa ilu naa ti tẹ laipẹ yii sọ fawon oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pe awọn owuyẹ kan ni wọn waa fọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, ti ikọ ọlọpaa kan ti wọn n pe ni ‘Quick Intervention Squard’, si ti lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ.
Alukoro ọlọpaa naa sọ pe, Ekpiri ko b’awọn jiyan rara lakooko tawọn fọwọ ofin mu un, to si tun ti jẹwọ loju-ẹsẹ fawọn pe, loootọ loun ta ọmọ oun to jẹ ọmọọdun mẹsan-an ọhun lẹgbẹrun lọna irinwo Naira fun onibaara kan bayii.
Ninu ọrọ rẹ nigba to n sọ fawọn oniroyin nipa ohun to gbe e de ọdọ awọn ọlọpaa, Ekpiri paapaa ti n kabaamọ lori ohun to ṣe naa, o ni eṣu lo sun oun debi iwa palapala bẹẹ, ati airowo jẹun. O ni lasiko ti ebi buruku kan fẹẹ gbẹmi oun danu loun ba kuku pa ọkan pọ, toun si gbe ọmọ naa ta danu lowo pọọku pẹlu ireti pe b’oun ba ṣi wa loke eepẹ, oun maa bimọ miiran.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, C.P. Ọlatoye Durosinmi, ti loun nífẹẹ si ẹjọ Ekpiri naa, o si ti paṣẹ pe ki wọn tete pari iwadii nipa ọrọ rẹ, ki wọn si foju rẹ bale-ẹjọ ni kia.
Bakan naa lo rọ obi atawọn alagbatọ gbogbo pe tita ọmọ wọn lowo pọọku kọ lo maa yanju oke iṣoro wọn, ṣugbọn ki wọn nigbagbọ pe awọn ọmọ ọhun yoo diru, digba fun wọn lọjọ iwaju.