Tinubu paṣẹ gbigba owo-ori tuntun lọwọ gbogbo onimọto lọdọọdun

Faith Adebọla

Bi ko ba si ayipada kankan, bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, awọn onimọto pata, ibaa jẹ ti aladaani tabi tabi ti ileeṣẹ, titi kan eyi ti wọn fi n gbero, yoo bẹrẹ si i san ẹgbẹrun kan Naira, (N1,000) lọdọọdun sapo ijọba apapọ lati le gba iwe-ẹri ‘emi ni mo ni in’ tawọn eleebo n pe ni Proof of Owership Certificate, aijẹ bẹẹ, ijọba yoo fọwọ ofin mu wọn.

Owo-ori jijẹ oni-nnkan yii ki i ṣe fawọn onimọtọ nikan, wọn ni gbogbo ẹni to ba ti ni nnkan irinna pata lo gbọdọ bẹrẹ si i san owo naa sapo ijọba, titi kan awọn onikẹkẹ Maruwa atawọn ọlọkada pẹlu, ko si ti i daju boya ọrọ naa yoo kan awọn onikẹkẹ afẹsẹwa naa.

Nibi tọrọ naa lagbara de, ori nnkan irinna kọọkan ni ẹni to ni-in yoo ti san owo-ori tuntun yii, leyi to tumọ si pe ẹnikan tabi ileeṣẹ kan to ba ni ọkọ ayọkẹlẹ meji, ati kẹkẹ Maruwa mẹta, pẹlu ọkada kan, gbọdọ gbaradi lati san ẹgbẹrun mẹfa sapo ijọba lori awọn dukia rẹ wọnyi, bi ọdun kan ba ti si tẹnu bọpo, owo naa yoo tun di sisan lakọtun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, ni Akọwe agba ni ileeṣẹ to n ri si eto irinna ati igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni AbdulHafiz Toriọla, sọrọ yii di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Alausa, Ikẹja.

Ọkunrin naa sọ pe: “Inu mi dun lati kede pe eto kan maa bẹrẹ iṣẹ laipẹ yii lati tubọ jẹ ki aridaju wa nipa ẹni to ni dukia irinna, eyi ti wọn n pe ni Proof of Ownership Certificate (POC), nibaamu pẹlu awọn alakalẹ to maa jẹ ki aabo, aridaju ati ijihin wa lẹka eto igbokegbodo ọkọ kari orileede yii.

“Igbesẹ tuntun yii wa nibaamu pẹlu iwe ofin irinna ojupopo nilẹ wa, National Road Traffic Regulation, tọdun 2012, ti wọn ti ṣatunṣe si, idipọ kọkandinlọgọrun-un, isọri kẹtalelaaadọrin, eyi to kan an nipa fun gbogbo oni-nnkan irinna lati niwee-ẹri ‘nnkan mi ni’ yii.”

Akọwe agba naa tun ṣalaye pe eto sisan owo-ori tuntun yii maa jẹ kawọn le ni akọọlẹ to peye nipa gbogbo nnkan irinna pata lorileede yii, tori awọn maa lo anfaani naa lati ṣakọọlẹ gbogbo nnkan pataki to yẹ kijọba mọ nipa nnkan irinna kọọkan.

O ni ibi ipade nipa eto irinna lorileede yii tawọn ṣe lọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, lawọn ti mu aba naa wa, Aarẹ Tinubu si ti fọwọ si i.

Ẹ oo ranti pe ọfẹ ni ileeṣẹ ẹṣọ oju popo, iyẹn Federal Road Safety Corps (FRSC) maa n fawọn to ba ṣẹṣẹ ra mọto niwe-ẹri POC ọhun titi di ba a ṣe n sọ yii.

Amọ latinu oṣu Keje to wọle de tan yii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọnu ẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Leave a Reply