Nitori Akeredolu, awọn ọba alade wọle adura l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọba alade nipinlẹ Ondo ti wọle adura nitori ilera Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu.

Gbogbo awọn oriade ọhun ni wọn pejọ si gbọngan koko to wa lọfiisi gomina, Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, lati woju Ọlọrun lori ọrọ ailera Gomina Akeredolu. Eto adura yii ni wọn ṣe nilana ẹṣin Kirisitiẹni, Musulumi ati abalaye.

Olujigba ti Ijigba, Ọba (Ẹniọwọ) Luyi Rotimi, lo ṣaaju adura ni ilana ti awọn Kirisitiẹni, o gbadura ki Ọlọrun tete da sọrọ ilera Arakunrin, kì ara rẹ ya, ko le waa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ idagbasoke to n ṣe lọwọ nipinlẹ Ondo.

Aṣoju Imaamu agba fun Akurẹ, Alaaji Yusuf Agbẹsinga, ti i ṣe Imaamu mọsalaasi Gágà, lo ṣáájú adura ti wọn gba ni ilana ẹṣin Musulumi, gbogbo wọn ni wọn si jọ gbohun adura wọn soke si Ọlọrun Allah fun Aketi ati ipinlẹ Ondo lapapọ, nigba ti Abodi ti Ikalẹ, Ọba G. B. Faduyile, naa gbadura fun gomina nilana ẹṣin abalaye.

Deji tilu Akurẹ, to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọba alade nipinlẹ Ondo, Ọba Aladetoyinbo Aladelusi, ni awọn pinnu lati ko ara awọn jọ lọjọ naa lati woju Ọlọrun nitori awọn gbagbọ pe Oun nikan lo lagbara ati mu Arakunrin lara da.

Oba Aladetoyinbo juwe Aketi bii onigboya, asaaju ati ẹni to ti ṣiṣẹ takuntakun lori ọrọ aabo oun idagbasoke ipinlẹ Ondo lapapọ. O ni ohun kan ṣoṣo ti awọn le ṣe lati ran agba agbẹjọro naa lọwọ niru asiko yii ni ki awọn gbadura fun ilera rẹ, ko le waa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ rere to n ṣe lọwọ.

Deji ni inu awọn ọba alaye ko dun rara si bawọn oloṣelu kan ṣe fẹẹ maa lo anfaani ailera Akeredolu lati pokiki ara wọn, o rọ awọn iru ẹda bẹẹ ki wọn tete jawọ, nitori ko ni i dara ki wọn da rogbodiyan silẹ nipinlẹ Ondo nitori imọtara tiwọn nikan.

O ni asiko yii gan-an lo yẹ ki gbogbo awọn ti wọn n pariwo pe awọn nífẹ̀ẹ́ ipinlẹ Ondo ko ara wọn jọ pẹlu iṣọkan, ki wọn si gbadura kikankikan fun Gomina Akeredolu.

Leave a Reply