Awọn aafaa Ilọrin ti sọrọ: Idi taaye fi gba Yeye Ọṣun ree o

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn aafaa ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ awọn idi to mu ki aaye gba awọn Yeye Ọṣun niluu naa, ti wọn fi n ṣe bii ọmọ onilẹ.

Wọn sọrọ yii ni Yidi nla tiluu Ilọrin, layaajọ ọdun Ileya.

Wọn ni nnkan mẹta lo sokunfa aaye to gba awọn Yeye Ọṣun niluu Ilọrin, akọkọ ni pe awọn aafaa kan wa ti wọn o duro ti kewu, ti wọn n lọọ ṣoogun lọdọ wọn. Ẹẹkeji ni pe awọn ọmọ Ilọrin to n wa ipo tabi agbara naa maa n sa lọ sọdọ wọn. Bakan naa ni awọn iyawo ile naa n lọọ sa sabẹ wọn, to si yẹ ki gbogbo ẹ dopin bayii. Wọn ni ọpọ awọn ọmọ Ilọrin ni wọn n lọọ sa di Yeye Ọṣun, lai bikita ẹṣin Isilaamu ti wọn gbe lọwọ, ohun to jẹ wọn logun ni bi wọn ṣe fẹẹ di olokiki ojiji.

Wọn rọ Gomina AbdulRazaq, ko tete gbe igbesẹ ko to di ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ti wọn fẹẹ ṣe ọdun ọhun, tori pe ayẹyẹ ọdun Ọṣun ti wọn fẹẹ ṣe naa ko gbọdọ waye. O tẹsiwaju pe ki gbogbo awọn aafaa, olowo, onipo, ki wọn lo owo ati ipo wọn ki wọn saa ri i daju pe yẹyẹ ọdun naa ko waye niluu Ilọrin.

Ẹmia tilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Zulu-Gambari, ninu ọrọ tiẹ sọ pe ti wọn ba fẹẹ ṣọdun Ọṣun, ki wọn lọọ ṣe e niluu miiran, ki wọn ma ṣe e ninu Ilọrin, tori pe Ilọrin ko faaye gba ẹbọ ṣiṣe.

Leave a Reply