Ọwọ tẹ Ismail nibi to ti n fọle lọjọ ọdun Ileya

Faith Adebọla

Lọjọ ti erokero kan wọnu afurasi ọdaran ti wọn porukọ ẹ ni Ismail Ajibade Oguntunde yii, gende naa wa igi ati irin gbọọrọ meji kan, o si bẹrẹ si i fi ọra dudu we gbogbo ẹ pọ ko le da bii ibọn gidi. Boya lo sọ si i lọkan pe ẹwọn loun n kọwe si yẹn, amọ ọwọ ti tẹ ẹ nibi to ti n fi ibọn ayederu naa jale, o si ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ lahaamọ awọn ọlọpaa, nibi ti wọn ti n wadii iwa ọdaran to hu, wọn nile-ẹjọ lọrọ rẹ maa kangun si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fi fọto ati alaye nipa afurasi adigunjale yii ṣọwọ s’akọroyin ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, sọ pe awọn aladuugbo Ẹsiteeti Magodo, ti wọn n gbe Science Road Extension, ni Unilag Estate, ni wọn tẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa laago, wọn lawọn ẹlẹgiri adigunjale ti ya bo wọn ni nnkan bii aago mẹta ọganjọ oru, ki wọn waa gba wọn silẹ.

Kia lawọn ọlọpaa naa ti sare de adugbo ọhun, amọ bo ṣe ku diẹ ki wọn debẹ lawọn adigunjale yii bẹ latori fẹnsi kan somi-in, ti wọn sa lọ. Ọkan ninu wọn, Ismail, toun naa ṣi n pa radiradi lati wa ọna sa lọ lọwọ ba, ni wọn ba fi pampẹ ofin mu un.

Nigba ti wọn yẹ ara ẹ wo, wọn ba ibọn dẹndẹbula kan to jọra pẹlu eyi ibọn oyinbo ti wọn n pe ni mcCoy, amọ pako ati irin lasan ni wọn to pọ mọra wọn, ti wọn fi sẹloteepu dudu we mọran-in-mọran-in ko le da bii ibọn gidi.

Wọn tun ba aake mọnbe kan, tọọsi, kolo ọta ibọn dudu kan, atawọn nnkan mi-in ti wọn fi n jale lọwọ wọn.

Wọn ni kawọn ọlọpaa too de, awọn afurasi naa ti ṣe baba ọlọdẹ to n ṣọ ẹnu geeti abọwọle sinu ẹsiteeti naa leṣe gidigidi.

Ṣa, Alukoro Hundeyin ni Ismail ti n gbadun ẹran ọdun tiẹ lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa bayii, nibi to ti n ran wọn lọwọ lẹnu iwadii wọn, wọn si ti n ṣọna bi wọn yoo ṣe ri awọn yooku ẹ ti wọn sa lọ mu.

Lẹyin iwadii, afurasi ọdaran yii yoo lọọ ṣalaye ara rẹ fun adajọ, ibẹ ni wọn yoo ti kawe ofin si i leti daadaa, ki wọn too ṣedajọ ẹ.

Leave a Reply