Faith Adebọla
Ọkan ninu awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu ilẹ Hausa, to tun jẹ aworoṣaṣa ninu ẹgbẹ oṣelu ti Rabiu Kwankwaso da silẹ, New Nigeria People’s Party, NNPP, Alaaji Buba Galadima, ti sọ pe oun o reti ki Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ṣi wa nipo naa titi dasiko yii, o lo yẹ kijọba ti faya ẹ, ki wọn ti yọ ọ bii ẹni yọ jiga, tori ẹṣẹ rẹ buru ju ti gbogbo awọn lọgaa-lọgaa ti wọn gbaṣẹ lọwọ wọn lasiko yii lọ.
Galadima sọrọ yii laṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lori eto ori tẹlifiṣan Channels kan.
Ọkunrin naa ni loootọ, iwa atawọn ipinnu kan ti ọga agba banki apapọ ilẹ wa ti wọn ni ko ṣi lọọ rọọkun nile lasiko yii, Godwin Emefiele, ṣe ko bọ si i rara, amọ ta a ba ni ka wo o daadaa, ohun to ba fi mu ki wọn yọ Emefiele bii ẹni yọ jiga, ẹṣẹ ti Yakubu da buru ju tiẹ lọ, o si ti yẹ ki wọn le ohun naa danu bii ẹni l’aja, afi to ba jẹ pe ọrọ ọhun lọwọ kan abosi ninu lo ku.
Galadima ni niṣe ni Alaga INEC, Yakubu Mahmood, mọ-ọn-mọ tẹ ifẹ-ọkan awọn ọmọ Naijiria mọlẹ lasiko eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, o ni aburu nla lọkunrin naa ṣe fawọn ọmọ orileede yii.
Galadima ni: “Alaga INEC yii gbọdọ fipo silẹ dandan ni, o gbọdọ lọ ni, ohun ti Emefiele ṣe ko buru to tiẹ yii. Niṣe lo diidi lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan lati tẹ ifẹ-ọkan awọn ọmọ orileede Naijiria mọlẹ. Iwa ọdaran to buru jai lo hu, ohun to ṣe buru jọjọ” gẹgẹ bo ṣe wi.
Amọ nigba ti wọn beere lọwọ eekan oloṣelu yii nipa ero rẹ lori ẹjọ to wa ni kootu ta ko esi idibo aarẹ naa, Galadima fesi pe lero toun o, niṣe ni igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar, to jẹ oludije funpo aarẹ labẹ asia Peoples Democratic Party (PDP), ati oludije ti ẹgbẹ Labour Party, LP, kan n fasiko wọn ṣofo lori ẹjọ ti wọn pe lati yọ Bọla Tinubu nipo aarẹ.
O ni ta a ba wo o daadaa, loootọ ni magomago rẹpẹtẹ waye lasiko eto idibo wọnyi, ti awọn ojooro ati aiṣe-deede si po loniran-iran, amọ a o ti i gbọ ọ ri ninu itan orileede yii latọdunm 1979 pe ile-ẹjọ yẹ aga mọ aarẹ adiboyan eyikeyii nidii.
O ni: “Oloṣelu wo lẹyin ti gbọ ri pe o jare bọ ni kootu lori atako si esi idibo aarẹ lati ọdun 1979? Ki lo de ta a maa maa fowo wa, owo to to biliọnu mẹwaa tabi biliọnu mẹẹẹdogun ṣofo lasan, tori a ti n gbọ lori ẹrọ ayelujara bayii p’awọn eeyan kan ti n na obitibiti owo fawọn igbimọ tiribuna ti wọn n gbọ ẹjọ wọnyi. Iru owo kọngbẹ yii lo yẹ ka tete bẹrẹ si i fi mura silẹ de eto idibo tọdun 2027.”
Bẹẹ ni Galadima wi o.