O yẹ ki Aarẹ Tinubu dunaa-dura pẹlu awọn afẹmiṣofo ti wọn ronupiwada ni–Ahmad Yerima

Adeoye Adewale

‘‘Ki i ṣe pe mo jẹ baba isalẹ tabi bakan fawọn janduku afẹmiṣofo gbogbo to n yọ alaafia orileede yii lẹnu, ṣugbọn ohun ti mo ro ni pe o yẹ ki Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, gbe igbesẹ akin lati ba aw­ọn janduku ti wọn ti ronupiwada loootọ dunaa-dura, ki wọn le wa ojutuu sohun aburu gbogbo to n ṣẹlẹ lorileede wa. Bi Aarẹ Tinubu ba le gbe ọrọ ti mo sọ yii yẹ wo daadaa, o ṣee ṣe ki wahala awọn janduku ọhun dinku jọjọ laarin ilu, ko sohun ti ko ṣee ṣe fun ijọba, awọn kan ti ṣe e siwaju, o si yọri sibi to daa fun wọn, bi Aarẹ Tinubu naa ba ṣe e, ko sohun to buru nibẹ rara.’

Gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Alhaji Ahmad Sani Yerima lo sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, lẹyin to lọọ ki Aarẹ Tinubu ni ọfiisi rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Ninu ọrọ rẹ ni Yerima ti sọ pe lara ọna kan ṣoṣo ti Aarẹ Tinubu fi le tete kapa eto aabo nilẹ yii ni pe ki ijọba rẹ ba awọn janduku afẹmiṣofo ti wọn ti ronupiwada dunaa-dura lori ohun gan-an ti wọn n fẹ, ki wọn si ṣikaa gbogbo adehun to ba wa laarin awọn mejeeji lẹyin ipade naa lo daa ju lọ.

Yerima ni, ‘Ma a rọ awọn alaṣẹ ijọba orileede yii pe ki wọn jẹ ki asọye ati eyi to dan mọran daadaa wa laarin wọn atawọn janduku afẹmiṣofo gbogbo ti wọn ti ronupiwada, ki alaafia le jọba laarin ilu. Ko sohun meji ti gbogbo araalu fi gboṣuba fun iṣakooso ijọba Oloogbe Musa Ya’adua daadaa lọdun 2007 ju pe o fopin si ọrọ awọn agbebọn gbogbo ti wọn n dalu ru lagbegbe Niger/Delta, gbara to ti nawọ ifẹ sawọn agbebọn naa ni gbogbo nnkan ti lojutuu lagbegbe naa pata.

Eyi paapaa lo yẹ ki Aarẹ Tinubu ṣe bayii, ṣe lo yẹ ko ranṣẹ pe ojulowo awọn janduku gbogbo ti wọn ti ronupiwada, ki wọn si jọọ sọ asọye daadaa, lẹyin naa ni ki Aarẹ Tinubu mu gbogbo ileri yoowu to ba ṣe fun wọn ṣẹ pata.

‘‘Ki i sohun ti ijọba Aarẹ Tinubu ko le ṣe rara, iyẹn bo ba fẹẹ ṣe e, ki i ṣe pe mo n ṣegbe lẹyin awon janduku afẹmiṣofo ọhun rara, oju mi ko gba a bọrọ eto aabo ṣe n lọ lorileede wa ni mo ṣe sọrọ naa jade bayii. Eto aabo ṣe koko daadaa, lara ọna kan gboogi ti Aarẹ Tinubu fi le fopin sọrọ awọn janduku naa si ni pe ko ba awọn kọọkan ti wọn ti kuro ninu ẹgbẹ naa sọrọ, gbogbo ẹdun ọkan wọn pata ni ko si wa ojutuu si pata’.

Leave a Reply