Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, ti yan CP Ẹbun Oluwarotimi Adelesi gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa tuntun fun ipinlẹ Kwara, to si ti bẹrẹ iṣẹ bayii lati rọpo Kọmiṣanna tẹlẹ, CP Odama, toun naa ti ni igbega lati C.P si ipo AIG.
CP Adelesi ni obinrin akọkọ ti yoo kọkọ di kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, obinrin naa ti fitan balẹ bayii.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi ẹ mulẹ pe ọga ọlọpaa patapata nilẹ yii ti fi CP Adelesi ṣọwọ si Kwara gẹgẹ bii Kọmiṣanna tuntun, lẹyin ti Odama ti ni igbega lati ipo CP si AIG.
O tẹsiwaju pe ninu atẹjade kan ti Alukoro patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii, CP Ikechukwu Ani, fi sita ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, to kọja yii, lo ti kede iyansipo Adelesi, ati awọn kọmiṣanna meje mi-in lawọn ipinlẹ meje niluu Abuja, bii: Borno, CP Godwin Aghaulor; Ọyọ, CP Adebọla Ayinde Hamzat; Ebonyi, CP Augustin Ogbodo; Kẹbbi, CP Samuel Titus Musa; Anambra, CP Aderẹmi Olufẹmi Adeoye, Imo, CP Stephen Ọlarewaju, ati ipinlẹ Ogun, CP Alamatu Abiọdun Mustapha.