Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ibanujẹ ni gbajumọ sọrọsọrọ ori afẹfẹ nni, Ọladapọ Alao, tọpọ eeyan tun mọ si Ọmọ Ọba Ogo, wa bayii pẹlu bo ṣe padanu ololufẹ ẹ tootọ.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2023, ta a wa yii niyawo ẹ, Abilekọ Rachael Iyabọ Alao, faye silẹ to gbọrun lọ.
Gẹgẹ bi Ọmọ Ọba Ogo funra rẹ ṣe fìdi ẹ mulẹ fun gbogbo aye, laago marun-un aabọ idaji Sannde, ọjọ Aiku, lobinrin yii dagbere faye lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ to ti ṣe e.
Ọdun mọkandinlaaadọta (49) pere ni wọn larẹwa obinrin naa lo loke eepẹ ko too lọ.
Ọkunrin sọrọsọrọ to padanu ololufẹ ẹ yii waa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n ba a kẹdun ipapoda
iyawo ẹ kuu aduroti.
Bẹẹ lọ gbadura pe nnkan rere loun yoo fi san an fun gbogbo wọn.