Ọkunrin yii ti dero kootu, afọku igo lo fi n le iyawo ile kan kiri adugbo

Adeoye Adewale

Pe ko tiẹ ri ọrọ gidi kankan sọ lori awọn ẹsun iwa ọdaran meji ọtọọtọ ti wọn fi kan an, adajọ ile-ẹjọ Magisireeti kan niluu Ọjọ, nipinlẹ Eko, Onidaajọ D.S Odukọya, ti ni ki wọn lọọ ju Ọgbẹni Peter Ẹbunọla, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn sọgba ẹwọn, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira gẹgẹ bii owo itanran fun pe o n fi afọku igo le iyaale kan, Abilekọ Rashidat Ọlaitan, to n gbe lagbegbe Ishashi, nijọba ibile Ọjọ, nipinlẹ Eko, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Ẹsun iwa ọdaran meji ni Agbefọba, Esther Adesulu, to foju Peter ba ile-ẹjọ  fi kan an niwaju adajọ naa.

Ẹsun akọkọ ni pe Peter n fi afọku igo le iyaale kan kaakiri aarin ilu, ati pe o tun da wahala nla  kan silẹ lagbegbe naa. Gbogbo awọn ẹsun yii ni wọn sọ pe o lodi sofin tijọba Eko n lo, bẹẹ ni ijiya si wa fun un.

Ninu alaye rẹ nile-ẹjọ, agbefọba ni, ‘‘Iwọ Peter, to o n gbe lagbegbe Ishashi, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, fi afọku igo le iyaale kan, Abilekọ Rashidat Ọlaitan, kaakiri adugbọ lakooko ti ede aiyede kekere kan bẹ silẹ laarin yin. Ohun to o ṣe yii ki i ṣe nnkan to daa rara, ṣe ni iyaale naa fara pa gidi, to si jẹ pe ọsibitu aladaani kan lo ti laju saye. Ijiya nla lo wa fun awọn ẹṣẹ to o ṣẹ yii.

Nigba ti adajọ n beere lọwọ ọmọkunrin naa boya o jẹbi tabi ko jẹbi, Peter ni oun ko jẹbi rara, bakan naa lo rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ naa pe ko ṣiju aanu wo oun lori ọrọ yii.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ D.S. Odukoya faaye beeli silẹ fun Peter  pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira ati oniduuro meji ọtọọtọ, ti wọn si gbọdọ ni awọn dukia to jọju lagbegbe naa.

Ṣa o, o ni bi Peter  ko ba tete ri awọn ohun ti yoo fi duro naa, ki wọn lọọ ju u sọgba ẹwọn kan niluu Eko, o si sun igbẹjọ mi-in sọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply