Monisọla Saka
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun yii, ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom tẹ afurasi kan, Prince Thursday Okon, nitori bo ṣe ran awọn ajinigbe si ọga to n ba ṣiṣẹ tẹlẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọlatoye Durosinmi, ṣalaye lopin ọsẹ to kọja yii pe Okon pẹlu awọn afurasi meji mi-in ni ọwọ tẹ, nitori bi wọn ṣe lọwọ ninu bi ọga agba fasiti aladaani kan nipinlẹ Akwa Ibom, ṣe dawati.
Okon lo lọọ lẹdi apo pọ mọ awọn ọrẹ ẹ, Saviour Sunday Luke, ati Richard Friday, lati ji ọga ẹ atijọ gbe, lẹyin tiyẹn da a duro lẹnu iṣẹ latari bo ṣe n yọwọ kọwọ.
Lasiko to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, kọmiṣanna yii sọ pe, “Ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ji ọga agba fasiti aladaani kan nipinlẹ Akwa Ibom yii gbe lasiko to n dari lọ sile ẹ.
Ọjọ meji lẹyin ẹ, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, kan naa, lawọn ẹka ti wọn n gbogun ti iwa ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, nawọ gan ọkunrin kan to n jẹ Prince Thursday Okon, lẹyin ọpọlọpọ iwadii. Ọkunrin yii ni wọn lo ti figba kan ṣiṣẹ labẹ ẹni ti wọn ji gbe yii ri, amọ ti ọga ẹ gbaṣẹ lọwọ ẹ latari awọn iwa ọdaran kan ti wọn kẹẹfin pe o fẹẹ maa hu.
“Okon yii naa lo waa ko awọn ẹmẹwa ẹ ṣodi, ti wọn jọ gbimọ-pọ, to fi di pe oun pẹlu meji ninu awọn ti wọn jọ n huwa ọdaran, iyẹn Saviour Sunday Luke ati Richard Friday, ti gbogbo wọn jẹ ọmọ ilu Ikot Ebam, nijọba ibilẹ Mkpan Enin, nipinlẹ naa fi lọọ ji baba naa gbe.
Owo to le diẹ ni miliọnu kan ati igba Naira, ni wọn gba gẹgẹ bii owo itusilẹ ki wọn too fi ọkunrin naa silẹ. Ninu owo ti wọn gba yii ni igba Naira ati aadọta (250,000), ti ṣẹku sinu akaunti ẹni kan ninu awọn afurasi naa. Bẹẹ ni ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti wọn fi ṣiṣẹ laabi naa ti wa lakata awọn agbofinro”.
O sọrọ siwaju si i pe ọga agba ileewe giga Fasiti naa ti pada sọdọ awọn eeyan ẹ lalaafia, owo to si ṣẹku ninu owo itusilẹ naa ti wa nikaawọ awọn.
O ni awọn ṣi n ba iwadii lọ, dandan si ni kawọn afurasi lọọ kawọ pọnyin niwaju adajọ, tawọn ba ti pari.