Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi ti ṣafihan awọn afurasi ọdaran mẹrinlelogun (24) kan, wọn lawọn ni wọn pa oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa kan, Ọgbẹni Igwe Emmanuel, nipa oro, ti wọn si tun ji iyawo rẹ, Abileko Charity Igwe, gbe wọgbo lọ lọsẹ diẹ sẹyin.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje yii, ni wọn ṣafihan awọn kọlọransi ẹda ọhun ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi to wa niluu Abakaliki.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Falẹyẹ Ọlalẹyẹ, sọ fawọn oniroyin lasiko afihan naa pe gbara tiṣẹlẹ aburu ọhun ti waye lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sigboro ati inu igbo, wọn fimu finlẹ daadaa, bẹẹ ni wọn tun lo awọn ẹrọ igbalode kan bayii to n taṣiiri awọn afurasi ọdaran, wọn si fara balẹ daadaa ki ọwọ le tẹ gbogbo awọn amookunṣika ẹda naa, eyi lo jẹ ki wọn ri wọn ko lọpọ bẹẹ.
O darukọ diẹ ninu awọn tọwọ ba yii, ti wọn ki i ṣe olugbe ipinlẹ Ebonyi: Victor Ogbonna, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), Uche Christian, ẹni ọgbọn ọdun (30), Nelson Chukwu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), Ifeanyi Egwu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), Sylvester Ude, ẹni ogoji ọdun (40), Chinedu Aja, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), Chidera Onyebueke, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), Ude Nwabueze, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), ati Lucky Nweke Henry, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28). Gbogbo awọn wọnyi lo ni ilu Lokpanta, nipinlẹ Abia, ni wọn ti wa.
Ni ti Cyprian Nnachi, ẹni ọdun marundinlogoji (35), Anthony Onoaha, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), ati Ndubuisi Okeagu, ẹni ọdun marundinlogoji (35), wọn lawọn mẹtẹẹta yii ni wọn wa nidii bi wọn ṣe ji Ọgbẹni Stanley Dike ati Emeka Nwakwo gbe, awọn naa si ni wọn ṣakọlu sawọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ Ekumenyi, ti wọn maa n ṣayẹwo ọkọ nikorita olobiripo ti Union Bank, ati ẹka Oshiri, nibi ti wọn ti fibọn da ẹmi ọlọpaa mẹta legbodo lọjọsi.
Ohun to jẹ iyalẹnu ninu awọn tọwọ tẹ ọhun ni pe ṣọja ti wọn ti fẹyinti nidi iṣẹ ologun ni Anthony ati Ndubuisi yii, wọn lawọn ni wọn n ṣe agbodegba fawọn ajinigbe, awọn ni wọn n ba wọn gbowo nla lọwọ awọn mọlẹbi ti wọn ba fẹẹ yọ eni wọn kuro lakata awọn afurasi naa.
Kọmiṣanna naa ni iwadii ijinlẹ tawọn ṣe tun taṣiiri pe awọn mẹsan-an kan lara awọn afurasi ọdaran yii ni wọn ji awọn eeyan kan gbe pamọ si ibuba wọn to wa ni Opopona Okposi, l’Abakaliki, ti wọn si n fi wọn gbowo lọwọ awọn mọlẹbi wọn.
Wọn tun lawọn kan lara wọn jiiyan gbe pamọ sinu igbo kijikiju kan to wa ni Lokpanta, nijọba ibilẹ Umunneochi, nipinlẹ Abia, wọn lọọ ka wọn mọbẹ, wọn si tu awọn ti wọn mu sigbekun ọhun silẹ.
Kọmiṣanna fi kun un pe lara awọn nnkan ija oloro ti wọn n lo bii irinṣẹ, eyi ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ibọn AK-47 oriṣiiriṣii, ọta ibọn rẹpẹtẹ, awọn ibọn ilewọ ti wọn ti ki silẹ, oriṣiiriṣii ibọn ibilẹ, ati ọkọ ayọkẹlẹ Lexus 330 RX kan.
Wọn niwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn afurasi yii, gbogbo wọn lo si maa foju bale-ẹjọ laipẹ.