Hisbah fa ori awọn ọdọ ilu kan kodoro ni Borno, eyi lohun to fa a

Monisọla Saka

Ikọ Hisbah, ti i ṣe ileeṣẹ kan ti iṣẹ wọn fara pẹ tawọn agbofinro lawọn ipinlẹ apa Ariwa orilẹ-ede yii, ẹka ti ipinlẹ Borno, dabira lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun yii, lẹyin ti wọn yọ abẹ ifari ti irun ori awọn ọdọ kaakiri agbegbe nipinlẹ naa, ti wọn si n fa ori wọn kodoro.

Ninu atẹjade tawọn ọlọpaa Musulumi ipinlẹ Borno yii fi sita lopin ọsẹ to kọja yii ni wọn ti ni kaakiri awọn adugbo niluu Maiduguri, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa lawọn ti ṣorò, ati eto fọlumọ fawọn ọmọkunrin ilu naa.

Gẹgẹ bi Ibrahim Abdulkadir, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ naa ṣe wi, o ni oniruuru irun hanranhanran tawọn ọmọ naa gẹ sori, ati oriṣiiriṣii ọda ti wọn fi kun irun ori wọn lasiko ọdun Ileya to kọja yii ta ko iwa ọmọluabi, aṣa ati iṣe ipinlẹ Borno.

Igbesẹ ti wọn gbe yii lo ni yoo dena ẹgbẹkẹgbẹ ati iwakiwa laarin awọn ọdọ ilu naa.

Lara awọn agbegbe ti wọn ti lọọ ko awọn ọmọkunrin ti wọn gẹrun apapandodo fun nipinlẹ naa ni Baga Road, Gwange District, Keleri, Fori, London, Dala, Madiganeri, Mulai, Shehuri, Magumeri, atawọn agbegbe mi-in bẹẹ.

O ni ọdun Ileya to ṣẹṣẹ kasẹ nilẹ yii ni wọn tori ajọyọ ẹ ṣe irunkirun sori, amọ ileeṣẹ awọn gẹgẹ bii eyi to n gbogun ti iwa ibajẹ, ko ni i faaye gba iru iwa palapala bẹẹ laaye nipinlẹ Borno.

Ninu awọn fọto ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara, niṣe ni wọn yọ oriṣiiriṣii abẹ lewọ, ti wọn mu awọn ọmọ naa ni kọọkan, ti wọn si gẹ irun ori wọn mọ kodoro.

 

Leave a Reply