Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹgbẹ awọn awakọ ilu Iree, nijọba ibilẹ Bórípẹ́, nipinlẹ Ọṣun, ti rawọ ẹbẹ si Gomina Ademọla Adeleke lati da si wahala kan to n lọ lọwọ laarin wọn ati akọwe tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Oluọmọ Yinka Adeeọjọ.
Ilẹ kan ti awọn awakọ to jẹ ti Roodu (Road Transport Employers Association of Nigeria) ti n gbe ero, nidojukọ ile ifiweranṣẹ to wa niluu naa, la gbọ pe o da wahala silẹ.
Gẹgẹ bii iwe kan ti awọn awakọ naa fi han, ọdun 2010 ni awọn alakooso ijọba ibilẹ Boripẹ fun wọn ni ilẹ naa lati maa lo gẹgẹ bii paaki, Ọgbẹni Fatoye lo si fi ọwọ si i lorukọ kansu.
Alaga awọn awakọ naa, Sunday Adeọṣun, ṣalaye fun ALAROYE pe nigba naa lọhun-un, Oluọmọ Adeọjọ lọ sọdọ wọn, o ni ki wọn kuro lori ilẹ naa nitori oun ti ra a.
Adeọṣun ni, “Ọrọ naa di wahala debii pe a lọ si kootu, ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to fikalẹ siluu Ikirun, da wa lare, o si tun paṣẹ pe ki Adeọjọ san ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun wa.
“A n ṣiṣẹ wa lọ lai si wahala latigba naa, afi bi Adeọjọ tun ṣe de lẹyin ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii da Gomina Ademọla Adeleke lare lori idibo gomina, to si sọ pe ka kuro lori ilẹ yẹn.
“Lọjọ naa, o mu tepuruulu lọwọ ati ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa, ti wọn si n wọn ilẹ kaakiri. Ko pẹ sigba naa ni awọn adari ẹgbẹ ilu Iree, Iree Progressives Association pe wa sipade, wọn ni a ni lati kuro nibi ti a n lo yii.
“Ohun ti wọn sọ lọjọ naa ni pe latari idigunjale to waye niluu wa lọdun 2021, awọn banki mejeeji ti wọn ja lole nigba naa sọ pe ti awọn ba maa pada, paaki gbọdọ kuro nibi to wa. Asiko yii la bẹrẹ si i fura pe oun ti awọn kan ko ri gba lọwọ wa ni kootu ni wọn fẹẹ lo awọn aṣaaju ilu lati gba lọwọ wa.
“Ile itaja nla to jẹ ti Oluọmọ Adeọjọ ko jinna rara si awọn banki ti wọn n sọ yii o, wọn ko sọ pe ko kuro nibẹ. Ninu ile itaja rẹ yii, ile ounjẹ, ile ọti, ṣọọbu igẹrun, ibi ti wọn ti n fọ mọto ati bẹẹ bẹẹ lọ lo wa nibẹ.
“Bawo waa ni paaki tiwa to jinna si banki ṣe di ipenija fun aabo, ti ileetaja Adeọjọ yoo si duro nibẹ. O han gbangba pe ṣe ni wọn fẹẹ fi ọwọ ọla gba wa loju, wọn fẹẹ lo agbara oṣelu fun wa, bẹẹ awa ki i ṣe oloṣẹlu, gbogbo ẹgbẹ to ba wa lode ni tiwa.
“A mọ pe ẹlẹyinju aanu to fẹran mẹkunnu, to si koriira iyanjẹ ni Gomina Ademọla Adeleke, a n bẹ wọn ki wọn da si ọrọ yii, ọna atijẹ-atimu kan ṣoṣo ti a ni niyẹn, a ko fẹẹ di alainiṣẹ lọwọ nitori ọwọ to ba dilẹ lẹsu n bẹ lọwẹ’’.
Amọ ṣa, ninu awijare tirẹ, Oluọmọ Adeọjọ sọ fun ALAROYE pe awọn kan ti ko fẹran idagbasoke ati itẹsiwaju ilu Iree ni wọn wa nidii wahala naa, gbogbo ilu ni wọn si mọ iyatọ laarin awọn to fẹran ilu ati awọn ti ko fẹran ilu.
Adeọjọ ni ki i ṣe oun ni banki, bẹẹ ni ki i ṣe oun ni awọn aṣaaju ẹgbẹ Iree Progressives Association ti wọn sọ pe ki wọn kuro nibi ti wọn wa, o ni bi wọn ko tilẹ sọ pe ki oun gbe ileetaja toun naa kuro, sibẹ, wọn fun oun ni ofin ti oun gbọdọ tẹle.