Monisọla Saka
Lọjọ Aje Mọnnde, ọjọ kẹta, oṣu Keje ọdun yii, nile ẹjọ to n gbọ ẹsun to tibi ibo Aarẹ ọdun 2023 jẹ jade, Presidential Election Petition Court (PEPC) gba abajade iwadii ikẹyin tawọn aṣoju ajọ iṣọkan Yúróòpù lori eto idibo Aarẹ ilẹ Naijiria, European Union Election Observer Mission, ko wa siwaju wọn. Ninu ẹri ti wọn ko wa siwaju ile-ẹjọ yii, ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu eto idibo ati esi idibo ti wọn fi gbe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu wọle.
Bakan naa ni wọn tun gba esi ti oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, gbé kalẹ wọle gẹgẹ bi ẹri, pẹlu gbogbo bi Aarẹ Bọla Tinubu, ẹgbẹ oṣelu wọn, iyẹn All Progressives Congress (APC) ati ajọ eleto idibo ilẹ wa ṣe taku pe ko ri bẹẹ.
Ohun tawọn aṣoju EU sọ ni pe wọn ko ṣeto idibo naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, bẹẹ ni ko wa ni ibamu pẹlu bo ṣe yẹ ki ajọ INEC ṣe e, paapaa pẹlu bi wọn ṣe ti kọkọ ni eto idibo ọdun 2023 yoo yatọ si tawọn tatẹyinwa.
Ninu ọrọ tiẹ, ẹlẹrii ti olori awọn agbẹjọro Atiku, Chris Uche, pe ko waa sọrọ ṣalaye pe ki i ṣe gbogbo esi idibo Aarẹ ni ajọ INEC gbe sori afẹfẹ fawọn eeyan lati ri, titi di ọjọ kin-in-ni, Oṣu Kẹta ọdun yii, ati pe ni gbogbo igba naa, pẹlu bi esi idibo ko ṣe ti i pe nilẹ, wọn ti sare kede Aṣiwaju gẹgẹ bi ẹni to jawe olu bori.
O tẹsiwaju pe loootọ ni idiwọ wa lori awọn ohun elo naa, nitori bẹẹ si ni wọn ko ṣe lanfaani lati gbe esi idibo Aarẹ sori ayelujara awọn INEC, o lawọn INEC naa ko si gbiyanju lati fi iṣoro ti wọn n dojukọ to ileeṣẹ Amazon Web Services, to le yanju ẹ leti.
Lasiko ti Wọle Ọlanipẹkun, ti i ṣe olori awọn agbẹjọro fun Tinubu n ju ibeere si ẹlẹrii, alaye to ṣe ni pe loootọ ni idiwọ wa lati le gbe awọn esi idibo sori ayelujara lọjọ ti wọn n dibo gangan, amọ to ni lẹyin ọjọ naa, ko si wahala kankan mọ titi ti wọn fi ṣe akojọ esi idibo tan, ti wọn o si tun tori ẹ gbe e sori afẹfẹ.
Amọ ninu esi abajade iwadii ti ẹlẹrii fun ajọ INEC gbe kalẹ, Lawrence Bayọde, ti i ṣe olori ẹka ti wọn ti n ṣe amulo ati amojuto ẹrọ kọmputa, ṣalaye pe ida mọkanlelọgbọn pere ni esi idibo Aarẹ ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara ajọ INEC.
O tẹsiwaju pe ajọ naa ko ni ohun elo to jẹ mọ ẹrọ, ti wọn fi n ko esi idibo jọ, nitori bẹẹ si lawọn ko ṣe ṣamulo ẹrọ kankan, to jẹ iwe ati bairo lawọn adari eto idibo nipinlẹ kọọkan lo.
Pẹlu bi ẹlẹrii kan ṣe ti yọju, ati iwe mẹrin ti wọn ko silẹ gẹgẹ bi ẹri, ajọ INEC ti pari pẹlu ẹjọ ti wọn n jẹ lọwọ, eyi ti igbakeji Aarẹ tẹlẹ, to tun jẹ ondupo lẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar pe wọn.
Ninu ẹjọ to pe wọn yii lo ti ni magomago wa ninu eto idibo ti wọn ṣe, bẹẹ ni wọn pe wọn lẹjọ lori bi wọn ṣe kede Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria tuntun, lasiko ti wọn n ṣakojọ esi idibo lọwọ.
Lẹyin ti ajọ INEC ti jade sita lati wẹ ara wọn mọ yii, Aarẹ Bọla Tinubu, lo ku ti olori awọn adajọ to n gbọ ẹsun idibo, Onidaajọ Haruna Simon Tsammani, pa laṣẹ lati waa tako ẹsun ti wọn ka si i lọrun, lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje ọdun yii.