Ọlawale Ajao, Ibadan
Lati ọjọ Ẹti, Jimọ, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ko si agba ijoye nilẹ Ibadan mọ, gbogbo ijoye agba to wa nigboro ilu naa ti di ọba alade laaye ara wọn.
Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Moshood Ọlalekan Balogun (Okunmade Keji), funra ẹ lo jawe oye le wọn lori gẹgẹ bii ọba lagbegbe ti kaluku wọn joye le lori.
Ninu ọgba gbọngan Mapo, to wa niluu Ibadan leto oye ọhun ti waye.
Amọ ṣa, ninu awọn mọkọọkanla ti Ọba Balogun ti ṣeto lati fi jọba pẹlu iyọnda Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba-Oye (Sẹnetọ Rashidi Ladọja) ko ba wọn kopa nibi eto naa.
Ṣaaju ni Ladọja, ẹni to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe oun ko nifẹẹ lati jọba kekere kankan
Awọn agba ijoye to di ọba tuntun ọhun ni Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakunlẹhin; Tajudeen Ajibọla (Ọtun Baogun); Lateef Adebisi Adebimpe (Osi Balogun), Eddy Oyewọle (Osi Olubadan)
Kọlawọle Adegbọla (Aṣipa Balogun), Abiọdun Kọla Daisi (Aṣipa Olubadan) Dada Isioye (Ẹkẹrin Balogun)
Awọn yooku ni Hamidu Ajibade (Ẹkẹrin Olubadan); Dada Isioye (Ẹkẹrin Balogun); Adebayọ Akande (Ẹkarun-un Olubadan); ati Abiọdun Dauda Azeez (Ẹkarun-un Balogun).
Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Ologbe Abiọla Ajimọbi, lo ti kọkọ fawọn eeyan yii jọba lọdun 2017, Ọba Balogun ti i ṣe Olubadan to wa lori itẹ bayii naa wa lara awọn ijoye ti wọn fi jọba nigba naa lọhun-un laye Olubadan Saliu Adetunji, ṣugbọn ti awọn amofin bu ẹnu atẹ lu u, wọn ni ki i ṣe ojuṣe gomina ni lati jawe oye le ọba lori.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ igbade awọn agba ijoye Ibadan yii lọtẹ yii, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, sọ pe oun kọ loun fi awọn agba ijoye Ibadan jọba bi ko ṣe Ọba Balogun ti i ṣe Olubadan fúnra ẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn eeyan sọ pe gomina ipinlẹ Ọyọ fẹẹ gbe ade fun awọn oloye Ibadan, ṣe nnkan tẹ ẹ ri lonii niyẹn, Kabiesi Olubadan lo gbe ade fun awọn oloye wọn.
Olubadan ni olori awọn ọba ilẹ Ibadan, oun lo to lati fi ẹnikẹni joye, oun naa lo si fi awọn ijoye rẹ jọba.
“Mo ti ṣeleri tẹlẹ pe aawọ yoowu to ba wa lori ọrọ ade, a maa yanju ẹ. Emi ni mo sọ pe ko daa bii wọn ṣe gbera wọn lọ si kootu lori ọrọ yii nigba naa. Ṣugbọn nigba ti wọn ti gbe ọrọ kuro ni kootu, ti awọn funra wọn si ti sọ pe awọn ti ṣetan lati ṣe e, a ni lati ba wọn fọwọ si í.
“Mẹwaa ninu awọn agba oye mọkanla lo wa nibi lonii, ọkan ninu wọn ni ko gba ade. Ninu eto dẹmokiresi, ohun ti ọpọ eeyan ba se ni abẹ ge, awọn màìnọ́rítì kan maa sọ tẹnu wọn lasan ni. A ti gbọ ohun ti màìnọ́rìtì n sọ, ti nnkan ti a n ṣe yii ko ba si tẹ wọn lọrun, wọn le gba ile-ẹjọ lọ.
“A ti fi itan lẹlẹ lonii, awọn to ba lọ si kootu, wọn fasiko ara wọn ṣofo ni, nitori ohun ti gbogbo ijoye Ibadan fẹ ka ṣe la ti ṣe yii”.
O waa pe awọn ọba tuntun naa nija lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe faraalu wọn.
Ṣaaju l’Ọba Balogun ti ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bii igbesẹ ti yoo mu iyi ati agbega ba ipo Olubadan, nitori awọn ọba tuntun wọnyi ko kuro ni ipo igbimọ olubadamọran oun ti wọn ti wa tẹlẹ, ìyẹn ni pe dipo awọn agba ijoye to ti maa n gba oun nimọran tẹlẹ, awọn ọba alade ni yoo maa ṣugbaa yi oun ka latoni lọ.
Awọn lọbalọba kaakiri ilẹ Yoruba ni wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.
Lara wọn ni Oluwo tilẹ Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Adéwálé, ẹni to jokoo sẹgbẹẹ Olori Olubadan gbagbaagba; Olu Igboọra, Sabiganna ti Iganna; Alepata ti Igboho; Onido ti Ido, Alakinyẹle ti Akinyẹle, Oniroko ti Iroko; Olugbọ ti Ile-Igbọn; Alawaye ti Ado-Awaye; Onpetu ti Ijẹru, ati Onipẹẹ tipẹ, (ipinlẹ Kwara),
nigba ti Ọba Adedire Adewọle ti i ṣe Onifẹgunwa ti Ifẹgunwa, ni Ile-Ifẹ, ni ipinlẹ Ọṣun ṣoju Ọọni -Ile-Ifẹ
Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, Imaamu agba ilẹ Ibadan,
gbogbo baalẹ ati mọgaji ilẹ Ibadan lo peju pesẹ sibi eto ọhun, titi dori Baalẹ Oluyọle, Baalẹ Yẹmi Ogunyẹmi pẹlu
Iyalọja Ilẹ Ibadan, Alhaja Riskat Amerigun, ati bẹẹ bẹẹ lọ.