Monisọla Saka
Ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii si ni ti olohun. Lẹyin bii ọsẹ kan to ji mọto olowo nla Mercedes Benz GLB 250, ti wọn ni owo ẹ to miliọnu marundinlọgọta Naira, lasiko to loun fẹẹ tẹẹsi rẹ wo niluu Abuja, ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Delta ati ti Edo, ti pada tẹ ọkunrin to pera ẹ ni Henry yii, ṣugbọn ti orukọ ẹ gangan n jẹ Meshach Sinuphro.
Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni ọkunrin oniṣowo ọkọ ayọkẹlẹ kan, Muhammad Manga, figbe bọnu, to si tun lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe ọkunrin kan to n jẹ Henry, to n gbe lagbegbe Gwarinpa, ti gbe ọkan ninu awọn mọto toun n ta sa lọ nibi to ti n yẹ ẹ wo, ko too kowo ẹ silẹ.
Ọrẹ Manga, toun naa n ta mọto lo waa gbe ọkọ ti wọn jọ dunaa-dura si miliọnu marundinlọgọta Naira (55 million) yii nileeṣẹ ọrẹ ẹ, pẹlu adehun pe oun ni onibaara kan to fẹẹ ra a. Amọ to jẹ wọn o ti i rin jinna debi kan lasiko ti Henry loun fẹẹ tẹẹsi rẹ wo, ti ọrẹ Manga fi sọ fun un pe ko ya nile-epo, nitori oun fẹẹ gbowo lẹnu POS, kawọn le ra epo sinu ọkọ naa. Ni kete ti ọrẹ Manga sọ kalẹ ninu mọto bayii ni atilaawi wa mọto sa lọ.
Lẹyin ti wọn ti fẹjọ sun awọn ọlọpaa Abuja tan ni wọn ti kede pe wọn n wa ọkunrin naa.
Amọ ti Ọlọrun ṣe e ni riri niluu Asaba, nipinlẹ Delta, lọjọ keje, lẹyin tọkunrin naa ji ọkọ yii gbe lọ.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun yii, ni ọkunrin oniṣowo mọto yii gba ori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ lọ, pẹlu fọto ọkọ ti wọn ji ati ole to ji i gbe, lati kede pe awọn ti ri mọto naa, to si tun lo anfaani naa lati dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn ṣugbaa rẹ lori ọrọ ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe ọkọ nikan ni wọn kọkọ ri lagbegbe ijọba ibilẹ Ariwa Ughelli, nipinlẹ Delta, lai si ẹni to ji i gbe ninu rẹ, awọn agbofinro ko sinmi lori ọrọ naa titi tọwọ fi tẹ afurasi nipinlẹ Edo.
L’Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu keje ọdun yii, ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, fọrọ naa sita loju opo Twitter rẹ pe ilu Benin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Edo, lọwọ ti tẹ Sinuphro, to ji mọto naa gbe.
O ni wọn yoo gbe afurasi yii lọ sileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja laipẹ. Bẹẹ lo rọ awọn eeyan lati ri i pe wọn n fẹjọ iwa ọdaran sun awọn agbofinro.