Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọlọpọ dukia lo ṣegbe sinu abami ina kan to deedee sẹ yọ ni ijọba Ila-Oorun Ondo, to wa niluu Bọlọrunduro, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii.
Gbogbo awọn ti akọroyin ALAROYE fọrọ wa lẹnu wo ni wọn ni ko sẹni to le sọ ni pato bi ijamba ina ọhun ṣe bẹrẹ tabi ohun to ṣokùnfà rẹ. Wọn ni ohun ti awọn to wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ ijamba ina ọhun ti waye ṣakiyesi ni pe ina n jade lati inu awọn ile kan nibẹ.
Ọfiisi awọn ọga nla nla nijọba ibilẹ naa la gbọ pe ina abami ọhun ti ṣọṣẹ ju lọ. Ṣe lo jo ile tawọn ọfiisi yii wa pẹlu ọkan-o-jọkan iwe atawọn ẹru to wa ninu wọn kanlẹ.
Ninu ọrọ ẹni to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, Ọnarebu Akinkuotu Ọlawale, o ni oun nigbagbọ pe ina to deedee sẹ yọ naa ki i ṣoju lasan, bo tilẹ jẹ pe ko si iwadii to ti i sọ ni pato ohun to fa ijamba ina ọhun.
O ni iwoye awọn ni pe awọn eeyan kan ni wọn waa ki ina bọ olu ijọba ibilẹ naa, nitori idi kan to ye wọn, nitori lati bii ọdun mẹẹẹdọgun sẹyin ni ko ti si ina NEPA niluu Bọlọrunduro, bẹẹ o to oṣu mẹta ti awọn ti tan ina jẹnẹretọ kẹyin latari epo bẹntiroolu to gbowo lori.
O ni ile loun wa nigba ti awọn eeyan kan pe oun sori aago lati fi iṣẹlẹ naa to oun leti, ti oun si sare pe awọn panapana atawọn agbofinro ki wọn le ba awọn mojuto ọrọ naa kiakia.
Akinkuotu ni ida aadọrin gbogbo ileeṣẹ ọhun lo fẹ́rẹ̀ẹ́ jona tan ki awọn panapana too ri ina abami naa pa.
O waa rawọ ẹbẹ sawọn ọlọpaa ki wọn tete ṣe iwadii iṣẹlẹ naa, ki wọn si ri i daju pe ọwọ tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun, ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin.