Faith Adebọla
Orin, ‘Ko sohun tuntun labẹ ọrun mọ’, ati ọrọ tawọn eeyan maa n sọ pe, ‘ko sohun tọkunrin n ṣe tobinrin ko le ṣe ju bẹẹ lọ’ lo wọ ọrọ awọn afurasi ọdaran meji kan tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ṣẹṣẹ ba lopin ọsẹ to kọja yii, Philomena Ebe ati Justina Edison. Iṣẹ adigunjale lawọn mejeeji atawọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ti sa lọ bayii n ṣe. Gẹgẹ bawọn adigunjale ọkunrin mi-in ṣe maa n ṣe, ti wọn maa ba obinrin to ba wọ wọn loju lo pọ nibi ti wọn ba ti lọọ digunjale, bẹẹ ni awọn afurasi yii naa n ṣe. Wọn jẹwọ pe tawọn ba digunjale tan, tawọn ba ri ọkunrin to jẹ oju awọn nigbese, to san-an-gun daadaa, awọn maa fipa ni ki ọkunrin naa ba awọn laṣepọ tulaasi, dandan si ni ki tọhun ṣe e. Ko sọrọ pe ara oun ko dide nibẹ, tori oju ina kọ lewura n hu irun.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Omokuru, nipinlẹ Rivers, lọwọ ti tẹ awọn afurasi mejeeji yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Abilekọ Grace Iringe-Koko, ṣe ṣalaye fawọn oniroyin.
Wọn ni ẹnikan to kagbako awọn atilaawi yii, Ọgbẹni Patrick, lo lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo ohun toju rẹ ri lọwọ wọn, bi wọn ṣe digun ja a lole, ti wọn gba owo atawọn dukia ẹ, ti wọn si tun rẹn ẹn mọlẹ pe dandan ni ko ṣere ‘kinni’ fawọn, ati bi wọn ṣe ṣe e leṣe nigba ti ko le ṣe ‘kinni’ ọhun daadaa bi wọn ṣe fẹ.
Ọkunrin naa lo jẹ kawọn ọlọpaa mọ pe mẹjọ lawọn to ṣe akọlu soun, ọkunrin si wa laarin wọn. Oju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti ta mọra, ti wọn tọpasẹ awọn amookunṣika naa lọ, tọwọ si ba wọn.
Ki i ṣe pe ọwọ ba wọn nirọrun bẹẹ, Grace ni nigba tawọn ọlọpaa naa kẹẹfin wọn nibi ti wọn wa, wọn gboju agan sawọn agbofinro, awọn naa ṣi ṣe iṣe akọni pẹlu ibọn ọwọ wọn. Bi wọn ṣe n yinbọn fawọn ọlọpaa ọhun lawọn naa n yinbọn fawọn naa.
Nigbẹyin, awọn mẹfa ribi sa lọ laarin wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn ni wọn ti fara gbọta gidi, amọ ọwọ tẹ awọn meji yii, Justina ati Philomena, ti wọn tun n pe ni Philo.
Wọn lawọn tọwọ ba yii ti n ka boroboro fawọn agbofinro ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo. Wọn ti jẹwọ pe loootọ lawọn n digunjale, loootọ si lawọn n fipa ba ẹni to ba wu awọn ninu awọn tawọn ba ja lole laṣepọ. A gbọ pe wọn ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ lati mọ bi wọn yoo ṣe ri awọn to sa lọ mu.
Lara awọn nnkan ija ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi yii ni ibọn meji, oogun abẹnugọngọ, egboogi oloro ati owo rẹpẹtẹ kan ti wọn fura pe oko ole ni wọn ti ri i gba.
Ṣa, wọn ti taari awọn mejeeji sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, iwadii si ti n tẹsiwaju. Lẹyin iwadii ni wọn yoo foju wọn bale-ẹjọ gẹgẹ bi Iringe-Koko ṣe wi.