Adeoye Adewale
‘‘Ko sohun ti wọn sọ si mi lara ti ko ba mi mu rara, ti emi paapaa ba si ranti igba ti mo ṣi wa ni ọdọ, mo mọ pe mi o lo asiko naa daadaa, nitori mi o gbe awọn igbesẹ to yẹ ki n gbe nigba naa, mi o ṣe awọn ohun to yẹ ki n ṣe. Ohun to si fa eleyii ni pe mi o ni eeyan gidi lẹgbẹẹ, mi o ri ẹgbọn tabi aburo gba mi nimọran pe bo ṣe yẹ ki n ṣe niyi, eyi nidi ti mo fi ṣi ẹsẹ gbe, ohun lo si ṣe akoba fun mi lasiko ti mo wa yii’’.
Oṣere ilẹ wa kan to wa ni idubulẹ aisan bayii, Dayọ Adewumi, ti gbogbo eeyan mọ si Sule Suebebe, lo ṣe bayii sọrọ ninu fidio kan to gbe sita, eyi to fi n bẹ awọn eeyan to ti ṣẹ nigba to ṣi wa ni ṣango ode, pe ki wọn dariji oun, ki wọn gbadura foun, ki wọn si foju pa aṣiṣe oun rẹ. Ni pataki ju lọ, Suebebe ni ki ọpọlọpọ awọn obinrin ti oun ti ja sọlọpọn atawọn toun ti ṣeleri toun ko mu ṣẹ fun jọwọ, foju pa aṣiṣe oun rẹ.
Adewumi ni, ‘‘Mo kan n jaye lọ, awọn ibi to yẹ ki n mojuto, mi o mojuto o nigba yẹn, mo kan n jaye lọ ni. A dẹ n rowo nigba yẹ, ọsọọsẹ la n ri owo. Ṣugbọn ko si olutọna to le pe mi ko ṣọ fun mi pe lagbaja, bi o ṣe n ṣe yii, ko wa okay. Mi o ri ẹnikankan, ko si ẹgbọn to gba mi nimọran, ko si aburo, ko si mọlẹbi kankan to gba mi nimọran kankan. Emi naa waa ri ara mi bii ọmọ jayejaye. Mi o ki n sun’le, bi mo ba fẹẹ lọọ paarọ aṣọ ni mo maa n lọ sile. Bi mo ba dẹ ti paarọ aṣọ tan, aṣọ ti ma a tun lo fun ọṣe kan, ma a ti ko o dani.
‘‘Nitori naa, ẹ jọwọ nitori Ọlọrun, gbogbo ọmọ Naijiria, gbogbo ẹni ti mo ba ṣe, yala mo mọ tabi mi o mọ, ẹ dariji mi. Ori idọbalẹ lo yẹ ki n wa ki n ti maa bẹ yin, ṣugbọn ko si agbara fun mi, ẹ jọwọ, gbogbo ẹyin ti mo ba ṣe, paapaa ju lọ, ẹyin obinrin, ti mo ti ṣẹ, ẹ dariji mi.
‘‘Tori mo mọ, mo mọ pe mo ti ṣẹ ọpọlọpọ, paapaa ju lọ lori awọn obinrin. Mi o le ka iye awọn ọrẹbinrin ti mo ni, mi o mọ eyi ti mo ṣẹ, mi o le mọ eyi ti mi o ṣẹ ninu wọn. Niluu oyinbo ni, mi o mọ, mo fẹẹyan niluu oyinbo to bimọ fun mi, ati ọmọ ati iyawo, mi o ri wọn.
‘‘Ẹ jọwọ, ẹ dariji mi, ki ẹ gbadura fun mi, igba aimọ ni, mo ti di ẹni ọtun bayii, ẹ jọwọ, ẹ dariji mi. Emi paapaa gba pe mo ti ṣe aṣiṣe nla nigbesi aye mi, bi ẹnikẹni ba mọ pe oun bimọ fun mi, ti mi o gba ọmọ naa lọwọ rẹ lakooko ti wọn loyun fun mi, ẹ jọọ, ẹ gbe ọmọ naa wa fun mi, ma a gba a lọwọ yin bayii. Emi paapaa mọ pe ipase obinrin wa lara idi ti mo fi ṣubu yakata bayii, ẹ dariji mi, mi o tun ni i ṣe iru rẹ mọ laye mi’’.
Bi oṣere yii ṣe n bẹbe, bẹẹ ni ohun rẹ n gbọn, to si fẹẹ maa sunkun.