Adeoye Adewale
Lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni awọn ajinigbe kan tẹnikẹni ko ti i mọ ti ji alaga ẹgbẹ oṣẹlu APC nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Paul Ọmọtọsho, gbe lọ.
Ẹnikan to ni ki wọn forukọ b’oun laṣiiri to sọ nipa iṣẹlẹ naa sọ pe lojuna marosẹ Agbado si Imesi-Ekiti, nijọba ibilẹ Gbọnyin, ni wọn ti ji Ọmọtọsho gbe sa lọ, ti ko si sẹnikankan to mọ ibi ti wọn ji i gbe sa lọ.
Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni alaga ọhun gbe dẹrẹba rẹ kan lọ sile lagbegbe Ado-Ekiti, lasiko to n dari pada sile lawọn ajinigbe ọhun ti wọn ti lugọ de e lojuna naa bọ sita, ti wọn si yinbọn soke gbau-gbau, nitori pe wọn ti ko nnkan soju ọna ọhun, ti mọto Ọmọtọsho ko si le kọja, ni wọn ṣe raaye ṣilẹkun mọto rẹ, ti wọn si ji i gbe e sa lọ patapata.
A tiẹ gbọ pe alaga ọhun, to jẹ ọmọ ilu Imesi-Ekiti, lo jẹ pe oun nikan ṣoṣo lo wa ninu mọto naa lakooko ti iṣẹlẹ laabi ọhun fi waye.
ALAROYE gbọ pe gbara ti awọn ajinigbe ọhun ti yinbọn lu taya mọto rẹ ni wọn ti ji i gbe gba inu igbo nla kan bayii to wa lagbegbe Iṣẹ-Ekiti. Wọn ko ti i pe awọn ẹbi rẹ lati beere ohun ti wọn n fẹ gan-an, bẹẹ ni wọn ko sọ idi ti wọn ṣe ji i gbe sa lọ rara.
Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ṣẹgun Dipe, toun naa sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe naa sọ fawọn oniroyin kan pe irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satidee, ọsẹ to kọja yii, ni wọn ji alaga naa gbe, ati pe awọn ti fọrọ iṣẹlẹ naa to awọn alaṣẹ ọlọpaa leti, ti ireti si wa daadaa pe wọn maa gba Ọmọtọsho silẹ laipẹ yii.
Bakan naa ni awọn agbofinro ti n ṣiṣe labẹnu bayii lati ri i pe ọwọ tẹ gbogbo awọn amokunṣika ti wọn lọwọ ninu iṣẹ laabi naa pata.