Faith Adebọla
O ti ṣe diẹ ti wọn ti n wa ọkunrin to porukọ ara ẹ ni Kennedy Amara yii, bo ṣe n fo lo n ba bii labalaba, bi wọn ṣe n gburoo ẹ s’Ake loni-in, kawọn agbofinro too debẹ, yoo ti sa lọ s’Oko lọla, tori oun naa ti fura pe wọn n wa oun latari iwa ọbayejẹ kan ti wọn fẹsun rẹ kan an. Niṣe lo n tan awọn opo, awọn ti oju ọkọ n pọ gbogbo pe oun maa fẹ wọn, tabi ba wọn wa ọkọ, amọ lẹyin to ba ti ba wọn laṣepọ tan, yoo fọgbọn ya fọto ihooho wọn pamọ, ni yoo ba bẹrẹ si i fi fọto ọhun halẹ mọ wọn lati gbowo nla lọwọ wọn, tabi ko maa ha awọn fọto naa kiri ibi to ba mọ pe awọn obinrin naa n jẹ si, lati fi wọn ṣẹsin. Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro ti too nigbẹyin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fọrọ yii lede lori ikanni tuita rẹ sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ta a wa yii, lọwọ to jagunlabi yii, o si ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n ṣewadii iwakiwa rẹ.
Wọn ni fọto ihooho obinrin opo kan ti wọn o fẹẹ darukọ lọkunrin yii fi ṣọwọ si ṣọọṣi tobinrin naa ti n jọsin, ti wọn si tori ẹ le obinrin yii ni ṣọọṣi ọhun, eyi lo si mu kawọn agbofinro bẹrẹ si i wa a kiri, titi tọwọ fi tẹ ẹ.
Wọn lalaye tobinrin naa ṣe fawọn ọlọpaa lasiko to lọọ fẹjọ oluku rẹ atijọ yii sun ni pe ọkunrin naa ṣi awọn ikanni ayederu kan sori Fesibuuku ati Wasaapu, nibi to ti maa n polowo pe oun le ṣeranwọ fawọn to ba n wa ọkọ tabi aya, oun le ba wọn ṣe e ki wọn pade ololufẹ gidi. Eyi ni yoo fi bẹrẹ si i gba gbogbo akọsilẹ awọn ẹni ẹlẹni ọhun bii fọto, orukọ, ọjo-ori, adirẹsi, ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ṣetan a ki i gbọn bii ẹni to n tan’ni.
Wọn lobinrin naa sọ pe lẹyin akoko diẹ lo jẹ pe ọkunrin naa funra ẹ lo dẹnu ifẹ kọ oun, oun si ri i bii ololufẹ gidi, loun ba gba fun un. Eyi ta a n wi yii pẹ, ọwọ ti wọwọ, ẹsẹ ti wẹsẹ, wọn ti bẹrẹ si i ṣere lọkọ-laya laarin ara wọn, laimọ pe ete buruku kan wa nikun afurasi ọdaran naa.
Afi bi ko ṣe ju ọjọ meloo kan ti aawọ de laarin wọn, wọn o si ri ọrọ naa yanju, niṣe lọkunrin yii tun ja obinrin opo tinu ẹ ti n dun p’oun ti rọkọ gidi tẹlẹ yii si okolombo, amọ ko fi mọ bẹẹ, o pinnu lati fi obinrin naa ṣẹsin, lo ba fi awọn fọto ihooho mama agbalagba yii ṣọwọ si ṣọọṣi tiyẹn ti n jọsin, pe ki wọn wo ihooho ọmọ-ijọ wọn.
Idojuti ati ifiniṣẹlẹya yii lo mu kobinrin naa lọọ fẹjọ rẹ sun ni tọlọpaa ti wọn fi n wa a, toun naa si n sa mọ wọn lọwọ titi tọwọ fi tẹ ẹ.
Wọn ni ki i ṣe meni, ki i ṣe meji awọn obinrin bẹẹ tafurasi ọdaran yii n ṣe ni ṣuta to ṣe yii.
Hundeyin ni Kẹnnedy ti wa lọdọ awọn bayii ṣa, nibi to ti n gbatẹgun tutu pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ, o si ti n ṣalaye ara ẹ bi wọn ṣe n bi i leere ọrọ. Lẹyin iwadii ni yoo lọọ fara han niwaju adajọ.