Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo, tun ti kọ lẹta mi-in si awọn aṣofin ipinlẹ naa, ninu eyi to ti gbaaye lati sun ọjọ ti yoo pada wọṣẹ siwaju.
Olori awọn aṣofin ọhun, Ọnarebu Ọladiji Ọlamide, lo fi eyi lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 ta a wa yii.
Nigba to n gba lẹta ọhun lorukọ awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ, Ọlamide ni igbesẹ ti Arakunrin gbe wa ni ibamu pẹlu abala aadọwaa (190) ninu iwe ofin orilẹ-ede Naijiria, eyi ti wọn ti satunṣe rẹ.
Abẹnugan ọhun ni Aketi tun kọ ọ sinu lẹta ọhun pe ki igbakeji oun, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ṣi tẹsiwaju gẹgẹ bii Adele-Gomina titi di igba ti oun yoo fi pada wale.
Ọlamide waa gbadura ki Ọlọrun tete dawọ le agba agbẹjọro ọhun, ko si pada wale layọ ati alaafia laipẹ ọjọ.
Olori awọn aṣofin ọhun ko waa sọ ni pato ọjọ mi-in ti gomina tun da ninu lẹta tuntun to ṣẹṣẹ kọ.
Gomina Akeredolu ti kọkọ fi lẹta kan ṣọwọ sileegbimọ aṣofin ọhun lọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ninu eyi to ti beere fun aaye ọsẹ mẹta lati lọọ fi tọju ara rẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje yii, lawọn eeyan n reti pe ko pada sẹnu iṣẹ ni ibamu pẹlu aaye to gba nigba naa.