Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Kẹwaa, oṣu Keje yii, ni ile-ẹjọ giga kan to filu Ilọrin ṣebujokoo ti ni ki awọn ọkunrin mẹta kan, Yusuf Ọlamilekan Ibrahim, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to jẹ ọmọ Ajerọmi, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Eko, Abdulazeez Taofeek Ademọla ati Nurudeen Abdulmajeed, lọọ fi ẹwọn oṣu mẹfa-mẹfa jura lori ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ti wọn fi kan wọn.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, lo wọ awọn afurasi naa lọ si kootu lori oniruuru ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn.
Mustapha Kaigama to ṣoju EFCC nile-ẹjọ lo ko awọn ẹri maa jẹ mi niṣo siwaju adajọ, o ni laaarin oṣu Karun-un, ọdun 2022, si oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni Yusuf Ọlamilekan lo orukọ oyinbo-binrin kan, Krissy Rivera, to n gbe ni ilu Amẹrika, fi lu ọkunrin kan, Keith, ni jibiti owo dọla rẹpẹtẹ niluu Ilọrin, eyi to ta ko iwe ofin ilẹ wa.
Bakan naa ni wọn ba miliọnu mẹsan-an Naira le diẹ ninu akanti Abdulazeez Taofeek Ademọla, laarin oṣu Keji si oṣu Kejila, ọdun 2020, ti ko si le ṣalaye bi owo ọhun ṣe jẹ, eyi to tumọ si pe o lu awọn eeyan kan ni jibiti ni. Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, ni wọn ni Nurudeen Abdulmajeed, lu oyinbo kan, Colby Myers, ni jibiti owo dọla niluu Ilọrin, eyi to ta ko iwe ofin ilẹ wa.
Awọn afurasi naa gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan awọn.
Lara awọn dukia ti wọn ba lọwọ wọn ni: ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan, awọn kọmputa agbeletan, ọpọ iPhone ati owo rẹpẹtẹ ninu akaunti wọn.
Adajọ Mahmoud Abdulgafar, paṣẹ pe ki awọn ọdaran mẹtẹẹta lọọ faṣọ penpe roko ọba fun oṣu mẹfa-mẹfa, pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Mandala, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
O fi kun un pe ki gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ wọn ati owo di ti ijọba apapọ.