‘Alailojuti ni Fayoṣe’

Jamiu Abaymi

Latari ọrọ ti gomina ipinle Ekiti tẹlẹ ri, Ayọdele Fayoṣe, sọ lọsẹ to kọja pe oun ṣiṣẹ ta ko Atiku Abubakar to jẹ oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ninu eto idibo aarẹ to kọja yii,

ọkan lara ọmọ igbimọ oloye ẹgbẹ oṣelu naa, National Executive Committee (NEC), Timothy Osadolor ti sọ pe awọn igbimọ adari PDP yoo ri si ọrọ naa laipẹ yii.

 Osadolor juwe Fayoṣe bii alainitiju eeyan.

O ni, ”Ṣiṣiṣẹ ta ko PDP ti Fayoṣe n ka boroboro bii ajẹ le lori yii ko jọ wa loju, alainitiju eeyan ni. Ohun to daju si ni pe ẹgbẹ oṣelu PDP yoo fesi si ọrọ rẹ laipẹ rara”.

Tẹ o ba gbagbe, lori eto tẹlifiṣan kan ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa ti sọ pe oun ko ṣe atilẹyin fun Atiku lasiko ibo aarẹ to kọja, o ni Aṣiwaju Bọla Tinubu ti APC loun ṣiṣẹ fun nitori awọn iwa ti Atiku hu.

Fayoṣe ni orile-ede Naijiria tobi ju ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC lọ, koda o tobi ju Asiwaju Bọla Tinubu lọ. O loun ki i parọ, oun ki i ṣeke, niṣe loun ṣiṣẹ ta ko oludije ẹgbẹ awọn lasiko idibo aarẹ to kọja naa.

 

Leave a Reply