Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii, ni fọnran fidio kan gba ori ayelujara, nibi ti wọn ti ṣafihan awọn afurasi ajinigbe mẹta kan ti wọn ti jona kọja sisọ ninu igbo kan lagbegbe Iwo, nijọba ibilẹ Ìsìn, nipinlẹ Kwara.
Ninu fidio yii ni awọn fijilante Igbomina, ni Kwara, ti sọrọ pe nigba tawọn ajinigbe n yọ awọn lẹnu ni awọn bẹ aara lọwẹ si wọn, ti mẹta ninu awọn ajinigbe naa ti wọn jẹ kikidaa Fulani si ku lalẹ mọju ni bii ọjọ mẹta sẹyin.
Bakan naa ni fidio miiran tun wa to ṣafihan awọn Fulani darandaran kan to n ṣedaro awọn eeyan wọn ti aara san pa ọhun, ti wọn si ni amuwa Ọlọrun ni, ki i ṣe lati ọwọ ọmọ ẹda Kankan, ati pe ko si ẹni ti yoo pe Ọlọrun lẹjọ.
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ idagbasoke ọmọ bibi iluu Òrò-Àgọ́, (ODU), to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn ẹgbẹ fijilante ti fi ọrọ iṣẹlẹ naa to awọn leti.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, sọ pe ileesẹ ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ naa, iwadii si n lọ lọwọ lori ẹ.
Nigba ti Alaga ẹgbẹ awọn fijilante ni Kwara, Saka Ibrahim, n ba ALAROYE sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, o ni bi awọn fijilante yii ṣe sọ aṣiri bẹ ẹ sita ko dara to, aimọye irufẹ nnkan aṣiri bii eleyii lawọn maa n ṣe, tawọn ko si ni i sọ ọ sita.