Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkan-o-jọkan awuyewuye lo ti n su yọ lori ọrọ kan ti wọn ni alaga apapọ fẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Abdullahi Adamu, sọ lori ailera Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ninu ipade kan ti wọn ṣe pẹlu gbogbo awọn alaga ẹgbẹ ipinlẹ kọọkan ni olu ile ẹgbẹ wọn to wa l’Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun ta a wa yii.
Ohun to fa awuyewuye ọhun ni iroyin ti akọroyin iwe iroyin ojoojumọ kan gbe, ninu eyi to ti ni alaga ẹgbẹ APC sọ nigba to n sọrọ pe aarẹ Akeredolu kọ sisọ, bẹẹ ni ko le gbọwọ tabi ẹsẹ nile-iwosan to ti n gba itọju.
Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo, Abilekọ Bamidele Ademọla Ọlatẹju, lo kọkọ fi aidunnu rẹ han nipa iroyin ọhun ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii.
Ọlatẹju ni oun gbagbọ pe iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbe kiri ọhun ko le sẹyin awọn oloṣelu kan ti wọn fẹẹ fọrọ ailera Aketi di gbajumọ ọsan gangan.
O ni alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, toun naa wa ninu ipade ọhun ti sọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ rara, nitori ko si igba ti iru ọrọ yii jade lẹnu Adamu lasiko ti awọn n ṣe ipade.
O ni ṣe ni inu Adamu dun adundẹyin nigba to gbọ pe ara gomina ọhun ti n ya, to si ni ki awọn gbadura fun un ko le tete pada wale lati waa tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ.
Kọmisanna ọhun ni ko si idi to fi yẹ ki akọroyin kan gbe iru ahesọ buruku yii jade nitori ko sewu rara lori ọrọ ailera Arakunrin. O ni agba agbẹjọro ọhun ṣi fi awọn ọrọ kan ransẹ sori ikanni igbimọ apaṣẹ ipinlẹ Ondo lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje yii.
O rọ awọn araalu lati kọ eti ikun si iroyin naa, ki wọn si maa fi adura ran gomina lọwọ, ko tete pada wale ni kete tawọn dokita ba ti fun un laaye.
Ninu alaye tirẹ, Isaac Kekemeke to jẹ alaga ana fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo naa kin ọrọ ti kọmisanna feto iroyin sọ lẹyin.
Kekemeke ni oun naa wa nibi ipade ọhun, ati pe iru ọrọ bẹẹ ko jade lẹnu Sẹnetọ Adamu to jẹ alaga awọn, o ni ohun to mu ki ọrọ Gomina Akeredolu jẹ jade ni igba ti wọn n sọrọ lori bi awọn agbebọn kan ṣe ji alaga ẹgbẹ APC ipinlẹ Ekiti gbe.
O ni lẹyin ti wọn sọrọ ọhun tan ni Adamu fi imọlara rẹ han fawọn eeyan ipinlẹ Ondo lori ọrọ gomina wọn to n gba itọju lọwọ l’Oke-okun, to si gbadura ki Ọlọrun tete mu un larada, ko le waa tẹsiwaju ninu iṣẹ ilu to n ṣe.
Epe ni Jimoh Ibrahim, iyẹn Ṣẹnetọ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati lọọ ṣoju awọn eeyan ẹkun Guusu ipinlẹ Ondo nile-igbimọ aṣofin agba l’Abuja, ki mọlẹ to n ṣẹ lati fi bi ọrọ ọhun ṣe ka a lara to han, o ni ki gbogbo awọn ti wọn ba n reti iku Aketi maa niso lọrun de e, nitori ọkunrin naa ko ti i ṣetan iku.
O ni airi-kan-ṣe-kan lo n yọ awọn eeyan kan lẹnu ti wọn fi n pariwo kiri lori ọrọ ailera Akeredolu, nitori ki i ṣe oun nikan ni oloṣelu àkọ́kọ́ ti yoo ṣaarẹ lasiko to wa lori ipo.
Ibrahim ni ọpọ oṣu ni Aarẹ Muhammadu Buhari to jẹ aarẹ ana fi ṣaisan ti nigba to ṣi wa nipo aarẹ, ti ko si sohun to ti idi rẹ yọ.
Adele Gomina, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ni gbogbo awuyewuye to n lọ lọwọ lori ailera Aketi ko ni i di oun lọwọ lati jẹ oloootọ si ọga oun.
Ayedatiwa ni o ye oun yekeyeke pe ṣe lawọn ọbayejẹ kan mọ-ọn-mọ fẹẹ da ede aiyede silẹ laarin awọn igbimọ iṣejọba nipasẹ iroyin ofege ti wọn n gbe kiri ori ayelujara.
O ni oun ati Aketi si jọ sọrọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje ta a wa yii, to si n dupẹ lọwọ oun atawọn ọmọ igbimọ iṣejọba to ku fun bi ohun gbogbo ṣe n lọ letoleto lati igba ti ko ti ṣi nile.
Nigba to n fun awọn asaaju ẹgbẹ APC lesi ọrọ wọn, Akọwe iroyin fun ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDD) nipinlẹ Ondo, Kennedy Peretei, ni o to akoko fun awọn to ba mọ nipa ipo ti ailera Aketi wa lati jade si gbangba, ki wọn si bun awọn eeyan ipinlẹ Ondo gbọ nipa rẹ, nitori eyi nikan lo le dena bi wọn ṣe n fi ọrọ to ṣe pataki naa ṣawada nile-ọti tabi nita gbangba.