Ọlawale Ajao, Ibadan
Niṣe ni ibẹru-bojo gba ọkan awọn arinrin-ajo to wa niluu Mẹka lọwọlọwọ lati ipinlẹ Ọyọ, latari bi wọn ko ṣe ti i mọ ọjọ ti wọn yoo pada si orileede Naijiria.
Lẹyin ọsẹ meji ti eto ọhun ti pari, awọn arinrin-ajo bii ẹgbẹrun kan (1000) lati ipinlẹ Ọyọ ni wọn ko ti i mọ ọjọ ti wọn yoo pada sile.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, gbogbo eto lati da awọn alaaaji wọnyi pada sile lo ti fori ṣanpọn.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alaga igbimọ awọn alalaaji nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Sayed Malik, sọ pe gbogbo ọna ti awọn n ṣan lati fi ko awọn eeyan ọhun pada lawọn eto kan tabi omi-in n ṣe idina fun.
O ni awọn ti yanju awọn iṣoro yii, ṣugbọn baaluu to yẹ ko ko awọn arinrin-ajo naa lo kọkọ ko awọn ero ti Nasarawa lọ, lẹyin to si de to yẹ ko ko awọn ero ipinlẹ Ọyọ, ṣe lo kọ lati ṣe bẹẹ.
Lara awọn ero to ṣi wa ni Mẹka ti ko ti i pada de ni ẹni to ti figba kan jẹ alaga igbimọ ọhun, Ọjọgbọn Kamil Koyejọ Kọleoṣo, atawọn mi-in bẹẹ.