Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan, Victory Ahiante Ehiremen, ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun igbimọ-pọ huwa idigunjale.
Nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Patrick Longẹ, n ṣafihan Victory, o ṣalaye pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni ọmọbinrin to jẹ akẹkọọ ni fasiti kan nipinlẹ Ọṣun huwa naa.
Longẹ ni ọmọkunrin kan lo lọ si agọ ọlọpaa to wa niluu Ikire, lọsan-an ọjọ naa, to si ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe ori ẹrọ ayelujara loun ati Victory ti pade.
Ọmọkunrin naa sọ fawọn agbofinro pe Victory sọ pe ki oun waa ki oun niluu Ikire, lati Eko ti oun n gbe. O ni bi oun ṣe de Ikire lọjọ naa ni Victory fọgbọn tan oun lọ si ile ọrẹkunrin miiran to ni.
Kọmiṣanna ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti ọmọkunrin naa de ile ọhun, awọn janduku ti wọn ti n duro de e lo ba nibẹ, wọn si lu u lalubami lẹyin ti wọn ja a sihooho.
Lẹyin naa ni wọn gba foonu rẹ, ti wọn si tiransifaa miliọnu kan aabọ Naira ninu owo to wa nibẹ. Lasiko ti wọn n fiya jẹ ẹ lọwọ lo sa mọ wọn lọwọ, to si lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.
Kia la gbọ pe awọn agbofinro bẹrẹ iwadii, ọwọ si tẹ Victory, bo tilẹ jẹ pe ọrẹkunrin rẹ ti Ikire ti sa lọ, ọwọ ba awọn alaabaṣiṣẹ rẹ meji; Ariyọ Abayọmi, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ati Adeleke Ọpẹyẹmi toun jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun.
Ninu ọrọ rẹ, Victory ṣalaye pe ko ti i to ọsẹ meji ti oun ati ọmọkunrin to n gbe niluu Eko naa pade ara awọn lori ẹrọ ayelujara, ṣugbọn oun funra rẹ lo sọ pe oun fẹẹ waa ki oun ni Ikire.
O ni nigba ti oun n ba a sọrọ lori foonu ni ọrẹkunrin ti oun ni niluu Ikire, Ayọbami Oyebanji, ti inagijẹ rẹ n jẹ Ifanla, ti gbọ, to si sọ fun oun pe ki oun jẹ ko wa siluu naa.
Victory sọ siwaju pe oun ko mọ pe Ifanla ni ero buruku sinu fun ọmọkunrin naa, lẹyin ti oun ati ẹ de ile Ifanla ti wọn ti bẹrẹ si i lu u ni ẹru ti n ba oun, bẹẹ ni wọn sọ pe ki oun maa lo sile.
O ni oun ko mọ pe wọn gba owo lọwọ ọmọkunrin naa, ṣugbọn Ifanla fun oun ni ẹgbẹrun lọna ogoji Naira pe ki oun lọọ fi ṣerun.
Victory sọ pe iṣẹ Yahoo ni Ifanla n ṣe, ati pe oun ko mọ pe iṣẹ ti ko dara ni iṣẹ Yahoo ti ọrẹkunrin oun n ṣe yii, nitori ọpọ eeyan lo n ṣe e.
Amọ ṣa, kọmiṣanna ọlọpaa ti sọ pe awọn eeyan naa yoo foju bale-ẹjọ ni kete tiwadii ba ti pari.