Loootọ ni mo ṣiṣẹ ta ko Tinubu lasiko idibo abẹle ẹgbẹ wa – Adamu

Monisọla Saka

Abdullahi Adamu, ti i ṣe Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti sọrọ lori ajọṣepọ oun pẹlu Aarẹ Bọla Tinubu, atawọn igbesẹ to gbe latẹyinwa lati ri i daju pe Tinubu ko depo aarẹ. L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii, ni Adamu sọrọ yii lori tẹlifiṣan Arise TV.

O ni kawọn too ṣepade apapọ ẹgbẹ awọn, ati ibo abẹle to waye loṣu Karun-un, ọdun 2022, ni awọn igbimọ amuṣẹṣe, National Working Committee (NWC), ti jan olori ileegbimọ aṣofin tẹlẹ, Ahmed Lawan, lontẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ awọn.

O ṣalaye siwaju si i pe awọn eekan ẹgbẹ, atoun funra oun, ko nipa lati ṣe ohunkohun ju ki awọn fọwọ si aba awọn igbimọ amuṣẹṣe lati fa Lawan kalẹ lọ.

O loun lodi si Tinubu gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ lẹgbẹ awọn, nitori onikaluku ni yoo ni ẹni to nifẹẹ si, bo si ṣe wa kaari aye niyẹn.

Amọ o ni ni kete ti ipo naa ti ja mọ Tinubu lọwọ lẹyin idibo abẹle lawọn ti gbaruku ti i, ko le ba a jawe olu bori lasiko ibo aarẹ ọdun 2023.

O ni, “Ootọ ni pe mi o ti Tinubu lẹyin, mi o dẹ le jiyan pe emi gangan ni mo gbe aba naa siwaju awọn igbimọ NWC.

Orukọ olori ileegbimọ aṣofin nigba naa, Ahmed Lawan, la gbe siwaju igbimọ ka a to dibo abẹle.

Oriṣiiriṣii nnkan lo waye nigba yẹn o, ati ni ọjọ ibo gangan. Agaga lẹyin ti wọn fa a kalẹ, nitori mo wa nibẹ, emi ni mo si dari gbogbo ẹ lọjọ yẹn.

“Nigba ti ilẹ ọjọ keji ibo abẹle yii si mọ, to ti ri i pe Tinubu ni yoo gbegba ibo aarẹ lẹgbẹ wa, gbogbo awọn ọmọ igbimọ (NWC) ni mo ko sodi, ta a gba ile Tinubu to wa ni Asokoro, Abuja, nibi yii lọ lati jẹjẹẹ atilẹyin wa fun un. A fi i lọkan balẹ pe gbogbo nnkan to ba wa ni ikapa wa la maa ṣe lati ri i pe agbara ti wọn gbe le e lọwọ wulo fawọn eeyan ilẹ Naijiria.

“Bẹẹ naa la ṣe nigba ti ipolongo ibo bẹrẹ, gbogbo wa la fọwọsowọpọ pẹlu ẹ, ta a si jọ dojukọ eto idibo naa titi ti gbogbo rẹ fi wa sopin, Ọlọrun si ṣe e, a ri iṣẹ ṣe fun un, ti ẹgbẹ wa pataki nni, APC fi moke”.

Adamu ni idi niyi to fi maa n dun oun nigba tawọn eeyan ko ba yin oun pẹlu awọn jankanjankan ẹgbẹ mi-in lori aṣeyọri Tinubu, to jẹ dipo bẹẹ, wọn yoo maa sọ kiri pe aarin awọn ko gun.

Leave a Reply