Ọmọ ẹgbẹ OPC mẹfa ku sinu ijamba ọkọ lọna Isẹyin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Mẹfa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples’ Congress, lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ kan to waye lọna to ti ilu Iṣẹyin ati Ado Awaye ja si Abẹokuta, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii.

Ọlọpaa kan ta a forukọ bo laṣiiri fidi ẹ múlẹ pe ere asapajude lo fa sababi ijamba yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ode pataki kan lawọn ẹgbẹ OPC n lọ lọjọ naa, wọn fẹẹ lọọ ṣewọde ta ko ijinigbe to n ṣẹlẹ lagbegbe Isẹyin, eyi to ti n di lemọlemọ, ni mẹfa ninu wọn fi kagbako iku ojiji.

Aaye ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan FADOK, to wa niluu Isẹyin, ni wọn kọkọ gbe oku awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọhun lọ ko too di pe awọn ẹbi onikaluku wọn gbe wọn

lọ siluu Eko ti wọn n gbe.

Bi awọn adari ikọ ẹgbẹ OPC to fẹẹ ṣewọde ọhun ṣe gbọ iroyin iṣẹlẹ buruku yii ni wọn fagi le eto naa.

Ẹ gbadura kẹ ẹ to gba ẹgbẹrun mẹjọ Tinubu, ko ma lọọ da bii ti Buhari ọjọsi – Shehu Sani

 

Leave a Reply