Ojooro nijọba apapọ fẹẹ fi pin owo iranwọ faraalu yii o-Gomina Kano

Faith Adebọla

 Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kyari, ti fi aidunnu rẹ han si erongba ati ilana ti ijọba apapọ fẹẹ lo lati pin ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira (N500 billion) owo iranwọ kaakiri awọn ipinlẹ gbogbo ni Naijiria latari ọwọngogo epo bẹntiroolu, o ni ojusaaju ati eru ti wọ ọrọ naa.

Yusuf sọrọ yii nipasẹ Igbakeji rẹ, Kọmuredi Aminu Abdulsalam Gwarzo, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keje yii, fawọn oniroyin nipinlẹ Kano, nigba to n gba awọn alakooso ẹgbẹ alajẹṣẹku ipinlẹ ọhun, Kano Cooperative Society, lalejo. O ni ọna tijọba apapọ fẹẹ gba ha owo naa, fọmula ti wọn fẹẹ lo lati pin in ti fi sibi kan ju ibi kan lọ, ati pe niṣe ni wọn fẹẹ fi igbesẹ ọhun ṣe ipinlẹ Eko ati ẹkun Guusu inu lọhun-un, iyẹn South-South, loore, ki wọn si rọ owo naa sapa ibẹ ju awọn ipinlẹ ati iha yooku lorileede yii lọ.

Ẹ oo ranti pe laipẹ yii ni ijọba apapọ ṣeleri lati ro awọn ileeṣẹ keekeeke atawọn okoowo alabọọde kaakiri awọn ẹkun ati ipinlẹ orileede yii, lojuna ati mu adinku ba inira to n koju awọn olokoowo ọhun lori yiyọwọ tijọba apapọ yọwọ ẹkunwo ori epo bẹntiroolu loṣu Kẹfa to kọja, wọn leyii yoo le ro awọn olokoowo naa lagbara, yoo si mu iṣẹ wọn rọrun, ati pe eto ti fẹrẹ pari lori iranwọ owo naa.

O ni ninu ilana to wa nilẹ bayii ti wọn fẹẹ lo, ida mẹtadinlaaadọta ninu ọgọrun-un (47%) owo naa ni wọn fẹẹ pin si ipinlẹ Eko nikan, wọn si fẹẹ pin ida mẹtadinlogun (17%) si ẹkun Guusu inu lọhun-un (South-South), ipin belenja belenja ni wọn si fẹẹ pin sawọn ipinlẹ ati ẹkun yooku.

Gomina ni: “Eyi o dara to rara, ko bofin mu, o si tẹ ofin loju gidi. A n fi asiko yii pe akiyesi awọn alaṣẹ tọrọ yii kan, titi kan awọn sẹnetọ ati awọn aṣoju-ṣofin wa gbogbo, lati ṣatunṣe sọrọ yii, ki wọn si da sẹria to ba tọ fẹnikẹni to ba wa nidii ipin ti ko dọgba ti wọn fẹẹ lo yii.”

Gomina ọhun ni ipinlẹ Kano to lero pupọ, ti ijọba ibilẹ rẹ si pọ ju ti ipinlẹ Eko lọ, lẹtọọ lati gba ju biliọnu mẹjọ taṣẹrẹ ti wọn fẹẹ pin fawọn lọ, eyi si le da họu-họu silẹ.

Leave a Reply