Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Awọn ẹsọ Amọtẹkun ilu Okitipupa ti fi pampẹ ofin gbe Fulani ẹni ogun ọdun kan ti wọn porukọ rẹ ni Abubakar Usman lori ẹsun fifi maaluu rẹ jẹ ire oko towo rẹ le ni miliọnu meji Naira.
Gẹgẹ bi ohun t’ALAROYE fidi rẹ mulẹ nipa isẹlẹ naa, aimọye iga ni wọn lawọn fulani darandaran ti ba awọn ire-oko ọkunrin agbẹ kan ti wọn porukọ rẹ ni Akinsuyi jẹ.
Baba ẹni aadọta ọdun naa ti kilọ fun awọn darandaran yii titi pe ki wọn jawọ ninu biba awọn nnkan ọgbin oun jẹ ṣugbọn ti wọn ko gbọ.
Bo ṣe kofiri ọkunrin naa to tun n fi maaluu rẹ jẹ awọn ẹgẹ olowo iyebiye to gbin sinu oko rẹ lọsẹ to kọja yii lo mori le ọfiisi ẹsọ Amọtẹkun to wa niluu Okitipupa lati lọọ fi ohun to n sẹlẹ to wọn leti.
Oju ẹsẹ ni wọn ti sare tẹ le oloko naa ti wọn si ba Fulani ọhun atawọn ẹran rẹ nibi ti wọn ti n pa itu meje ti ọdẹ n pa ninu oko oloko.
Nibẹ ni wọn ti mu un ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa ilu Okitipupa lọwọ, awọn maaluu rẹ la gbọ pe o si wa ni ikawọ awọn ẹsọ Amọtẹkun lasiko ta a fi n ko irooyin yii jọ lọwọ.